Okada Ban: Bàbá ọmọ ni ₦20,000 péré ni àwọn ọlọ́pàá fi lọ òun àmọ́ òun kò gbàá

Okada Ban: Bàbá ọmọ ni ₦20,000 péré ni àwọn ọlọ́pàá fi lọ òun àmọ́ òun kò gbàá

Arinfẹsẹsi ko kan maili a fi ki ọba oke maa sọ wa.

Baba ọmọdebinrin kan, Mariam Sobukola, ti asita ibọn ba, lasiko iwọde kan to waye lagbegbe Ipaja nilu Eko, lati tako bi ijọba se wọgile wiwa ọkada ati kẹkẹ, ti kigbe tọ BBC Yoruba wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko to n ba wa sọrọ, Mukaila Sobukola ni awọn ọlọpa to yinbọn mọ ọmọ oun ko tiẹ tara nipa isẹlẹ naa rara, oun nikan si ni oun n da gbọ bukata wahala yii.

Sobukọla ni dokita yọ ọta ibọn lara ọmọdebinrin naa, to si fi le oun lọwọ, amọ o ni, lọjọ kẹta ni dokita tun n bẹ oun pe ki oun mu ọta ibọn naa wa pada, ti wọn ko si fun oun mọ.

O fikun pe ọlọpa obinrin kan yọju si awọn sile iwosan, to si na ẹgbẹrun lọna ogun naira si awọn, amọ oun ko gbaa lọwọ rẹ, lati igba naa wa, awọn ko gbọ ohunkohun mọ.