Valentine: Wo bí àwọn òṣèré tíátà Yoruba ṣe ṣàyájọ́ olúlùfẹ́ ọdún 2020

Obinrin kan ninu asọ pupa ati funfun Image copyright I_am_shai

Ọjọ kẹrinla Oṣu Keji ni ayajọ ọjọ ololufẹ lagbaye, ọjọ ọhun si jẹ ọjọ ti ọpọ awọn eeyan ma n fi ifẹ han si ẹbi, ọrẹ ati ni paapaa julọ, awọn ololufẹ wọn.

Oriṣiriṣi ọna lawọn eeyan gba ṣajọyọ ayajọ ololufẹ ọdun yii, awọn oṣere tiata Yoruba naa ko gbẹyin ninu ọdun ololufẹ ọhun.

Bi awọn kan lara wọn ṣe n ki awọn ololufẹ wọn ku ọdun ololufẹ, lawọn mii n sọ pe wọn ko ni ololufẹ, lawọn mii ẹwẹ n ṣapejuwe ohun gangan ti ifẹ jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, ara ọ́tọ lawọn asọ ti wọn wọ fun ayajọ ololufẹ ọhun , awọn kan se wọ asọ alawọ pupa balau, lawọn kan ko si funfun, ti awọn miran si wọ asọ alarabara miran.

Image copyright aishalawal1

Alhaja Salawa Abẹ́ni, tii se olorin Waka, naa ko dagba ma labẹ, koda inu asọ pupa ni mama fọ si lati se ayajọ ifẹ, to si n ki awọn ololufẹ rẹ ku ayajọ ọdun falẹntai.

Image copyright officialsalawaabeni

Awoyemi Bukola Grace, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Arugba ṣeranti ọdun diẹ sẹyin nigba to pade ọkọ rẹ, Damola Olatunji.

O ni "Mo ranti ọdun diẹ sẹyin nigba ti mo pade arakunrin yii, mi o lero pe a o di tọkọ taya nitori ibi ti mo foju si, ọna ko gbabẹ."

Image copyright damolaolatunji

Ni ti ọkọ rẹ Damole, fidio lo fi fesi pada pe Bukola ni ololufẹ and alabadaro oun ti ko si si elomiran lẹyin rẹ.

Jumoke Odetola ni oun n wa okunrin ti yoo ba oun ṣe ọdun naa.

Bukọla Adeẹyọ gan ko gbẹyin ninu ajọyọ ọjọ ifẹ, asọ pupa lo ko si, to si sun silẹ pẹlu ayọ.

Image copyright bukola_adeeyo

Aisha Lawal loju opo Instagram rẹ sọ fun awọn tirẹ pe "Mo n ki yin ku ọdun ayajọ ololufe Falẹntain, ifẹ ati imọlẹ lo n jade lati ọdọ mi nibi."

Ni ti Funke Akindele ati ọkọ rẹ Bello ti ọpọ mọ si JJC Skiilz, ibi ayẹyẹ "LoveFest" ni wọn ti ṣe ọdun ololufẹ naa ni ilu Eko.

Image copyright funkejenifaakindele

Afeez Owo pẹlu iyawo rẹ Mide Funmi-Martins naa ko gbẹyin, bi wọn ṣe ṣe ajọyọ ọdun ololufẹ ọhun papọ.

Ọgbẹni Owo gbe aworan oun ati iyawo rẹ soju opo Instagram rẹ, to si kọ akọle kan pe "Ololufẹ mi."

E wo die lara awon aworan ti awọn oṣerẹ tiata Yoruba miran fi lede lati fi ṣajọyọ ayajọ ololufẹ naa.

Iyabo Ojo.

Image copyright iyaboojofespris

O ni "A de ku odun valentine oni o🤦, ọmọ araye o ni fi kayamata gba ọkọ lọwọ wa. Awa ti a o tii ni, a o ni se asedanu lori ọkọ ọplọkọ o."

Image copyright kunleafod

Ni ti Kunle Afod n tiẹ, kaadi lo se sita pẹ́lu aworan rẹ ninu rẹ, to si fi n ki awọn ololufẹ rẹ pe wọn ku ọdun ọjọ ifẹ.

Image copyright realmercyaigbe

Asẹ alawọ pupa ati funfun ni Mercy Aigbe wọ, to fi ki awọn ololufẹ rẹ ku falẹntai.

Image copyright Eniola Badmus

Ẹniola Badmus ree, to n ki yin pe ẹ ku falẹntai, ọpọ ẹbun ti awọn ololufẹ rẹ fi ransẹ si bii ẹbun ọjọ ifẹ, si lo patẹ rẹ yii, koda awọ pupa ati funfun lo ko si, to si dun wo.

Image copyright I_am_shai

Aworan eyi tun ga. Aworan mama kan ree ti Seyi Ẹdun gbe soju opo Instagram rẹ, eyi to n safihan pe ayajọ ololufẹ ko si fun awọn ọdọ nikan, tọmọde tagba lo wa fun.

Image copyright Kola Ajewole

Baba ati Mama Ire naa ko gbẹyin, Toyin Abraham ati Kolawole Ajewole, awọ̀n se ayajọ ololufẹ ni ranpẹ.

Kola ni bi Toyin ba pẹ laye di ọdun mọkanlerugba, oun naa fẹ ba gbe, to ba wa ku ọjọ kan ki dun naa pe, ki oun re kọja lọ, tori oun ko fẹ gbe ile aye laisi Toyin nibẹ. Ifẹ eyi tun ga ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionValentine: Ọkùnrin ní kí obìnrin má fún àwọn ní àwọ̀tẹ́lẹ̀ mọ́ bíi ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́