Amotekun: Àwọn aṣòfin ilẹ̀ Yoruba yóò ṣe ìjíròrò ìta gbangban lórí àbádòfin lọ́jọ́ Ajé

Amotekun Image copyright @ekitistategov

Gbogbo ile igbimọ aṣofin lawọn ipinlẹ Yoruba ni Naijiria ti ṣe tan lati ṣe ijiroro ita gbangba lori eto ikọ alabo Amotekun.

Agbarijọpọ awọn agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ekiti, Osun, Oyo, Ogun ati ipinlẹ Eko lo fi ọrọ naa lede.

Nibi ipade kan to waye nilu Ibadan lọjọ Kẹrinla Oṣu Keji ọdun 2020 ni wọn ti sọ pe ijiroro ita gbangba naa yoo waye.

Awọn agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin naa ṣepade lọjọ keji ti awọn Gomina ipinlẹ wọn ṣepade pẹlu ọga agba ajọ ọlọpaa ni Naijiria nipinlẹ Eko.

Awọn eeyan ọhun fẹnuko lati ṣepade pẹlu awọn adajọ agba nipinlẹ wọn lẹyin ijiroro naa, lati lee ṣayẹwo agbekalẹ abadofin naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni wọn ti sọ pe "Lẹyin ọpọ ijiroro ni a fẹnuko pe gbogbo ile igbimọ aṣofin nilẹ Yoruba ni lati gbe igbesẹ ati fi Amotekun sinu ofin ipinlẹ wọn."

Image copyright @news360info

Wọn tẹ siwaju pe "A ti kan nipa fun gbogbo ilẹ igbimọ aṣofin ilẹ Yoruba lati ṣe ijiroro ita gbangba nigba kan naa ni awon ipinlẹ wọn lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji ọdun 2020."

Bẹẹ ni wọn wa rọ awọn ara ilu lati peju sibi ijiroro ita gbangba ọhun lati le dasi ọrọ abo gbegbe wọn.

Wọn ti wa parọwa si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo to wa ni isinmi lati pada sẹnu isẹ, ki wọn le ṣeṣẹ lori ababdofin ọhun.