Lassa Fever: Ṣe ẹ rí eku tí ẹ̀ ń pè yẹn, oúnjẹ tó dára ni - ìyá ẹgbẹ́ àwọn eléwé ọmọ̀

"Ṣé ẹ rí ìwádìí tí wọn sọ pé lára eku ni wọ́n ti rí Lassa Fever yẹn, wọn ò tíí mọ ibi tí wọ́n ń lọ"."

Láti inu fídíò tó wà lókè yìí lẹ ó ti gbọ́ ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ àgbọ́ ya ẹnu sílẹ̀ lẹ́nu àwọn tí kò léè ju ìgbàgbọ́ wọn nínú ohun tí wọ́n ti ń ṣe tàbí jẹ látayé dáyé nù kí wọ́n wá gba ti òyìnbó tàbí ònímọ̀ ìlera wọlé - Fáàbàdà. Èèwọ̀ ni.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú lagbaye ni ko mọ pe apa ibi kan ṣi wa lorilẹ aye ti wọn ti n ta eku gbigbẹ iyẹn ni Naijiria

Awọn olutaja kan wa to jẹ pe loju paali, ni beeli, beeli, dọsiini dọsiini ni wọn ko ekute to ti ku sori igba wọn.

Bẹẹ ba de isọ awọn ti wọn n pe ni "Lekulẹja tabi Elewe Ọmọ", ẹ o ki aje ku ikalẹ.

Arabinrin Ṣakirat Jaiyesinmi ni gbogbo awọn ohun tawọn n ta yii ni wọn fi ń ṣe asejẹ fun eeyan to n woju Ọlọrun fun ọmọ, alaboyun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

"Emi ti mo n baa yin sọrọ yii, mo le jẹ eku mẹwa lojumọ, ti o dẹ ni ṣe mi ni nkankan".

Awọn ọdẹ lo maa n pa awọn eku yii wa fun awọn to n ta a.

Mama Ṣakirat ti o jẹ iya ẹgbẹ awọn elewe ọmọ ni ọja Ikorodu, ipinlẹ Eko, Naijiria ni "ṣe ẹ rí eku tí ẹ̀ ń pè yẹn, oúnjẹ tó dára ni", emi maa n jẹ ẹ daadaa... Shhhh. Àwọn olóyìnbó tó ń pariwo Lassa ò gbúdọ̀ gbọ́ èyí o.

Di to ninu nkan oni nkan, ẹ funra yin wo sii ki ẹ gbọ pabanbari ninu fidio to mbẹ loke iroyin yii.