Oluwo tí sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye láàrin rẹ̀ àti Agbowu tìlùu Ogbaagbaa

Àkọlé fídíò,

Oluwo ilu Iwo ba BBC Yoruba sọrọ lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba

Oluwo ilu Iwo Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ba BBC Yoruba nipa ohun to ṣẹlẹ laarin rẹ ati Agbowu ilu Ogbaagba.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to waye pẹlu Oluwo, Oba Alade naa ṣalaye pe ko si eleyi ti oun ko bọwọ fun laarin awọn ọba to wa labẹ ohun ṣugbọn iwa arifin awọn kan ti fẹ pọju.

Oluwo ni kii ṣe pe o wu ohun lati ma tahun si awọn ọba wọnyii ṣugbọn nigba ti wọn ba ti n tẹ ẹtọ awọn ara ilu mọlẹ nipa tita ilẹ lọna ti ko tọ, ohun ko ni le dakẹ.

''Ti awọn eeyan ba wa fẹjọ wọn sun mi, mo maa n sọ fun wọn pe ade mi lo wa lori wọn, ẹ ma ba wọn ja. Mo fi aye gba wọn gaan ṣugbọn laarin bii ọdun mẹrin bayii, arifin wọn ti pọju''

Oba Abdulrasheed nigba ti a beere nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn da apa si ọba Agbowu lara sọ pe ''Iro balawu ni wọn pa mọ mi''

Kii ṣe oni ni wọn ṣẹṣẹ n na ọpa si mi loju. Bẹẹ, eewọ ni ki wọn na ọpa si ọba. Nigba ti wọn fẹ ki ọpa bọ mi loju, ṣe ki n maa wo wọn niran ni?'.

Oluwo tẹsiwaju pe pupọ ninu awọn ọba to n doju ija kọ oun lo ti ta ilẹ awọn baba wọn tan ti wọn wa n wa awọn ilẹ ara ilu ti wọn a ta kun.

O pari ọrọ rẹ pe oun jẹ Oba to ni ifẹ ara ilu lọkan nitorinaa, oun ko ni gba ki ẹni kankan wa maa tẹ ẹtọ ara ilu mọlẹ.