Mike Ifabunmi, àwọn òṣèré Yorùbá kí BBC Yorùbá kú ayẹyẹ

Awon oṣiṣẹ BBC Yoruba
Àkọlé fídíò,

Mike Ifabunmi kí BBC Yorùbá kú ayẹyẹ ọdún méjì

Ọpọlọpọ awọn eeyan jankan jankan lo ti n fi ikini ku ayẹyẹ ọdun meji ranṣẹ si ileeṣẹ BBC Yoruba tẹ o si maa ri gbogbo rẹ loju opo wa bi oni ba ṣe n lọ.

Ka to wi ka to fọ ka to ṣẹju pẹrẹ, ọdun meji ti pe. Ọmọ kekere ana ti wa wa dagba.

Akanṣe eto pataki ti a ṣe fun ayẹyẹ ọdun meji BBC Yoruba loju opo Facebook wa niyii nisalẹ.

Awọn iroyin pataki taa ti mu wa fun un yin ko lonka lati igba ti BBC Yoruba ti bẹrẹ.

Àkọlé fídíò,

Iko BBC Yoruba tuntun

Kẹrẹkẹrẹ nigba ti igbohunsafẹfẹ ileeṣẹ BBC Yoruba ati kiko iroyin sori ẹrọ ayelujara bẹrẹ lọjọ naa lọhun, wẹrẹ wẹrẹ la n wọle si ọkan awọn eeyan.

Eyi ko tii dawọ duro bayii o koda, iroyin wẹrẹwẹrẹ ti di eyi ti wọn n rọ lu witiwiti lati ka bayii to bẹẹ ti okiki BBC Yoruba ti kan tayọ orilẹede Naijiria to si ti de gbgobo agbaye.

Iroyin lori eto oṣelu atawọn eekan Naijiria

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

BBC Yoruba taa ṣe ifilọlẹ rẹ ni dede ọjọ oni lọdun meji sẹyin, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji ọdun 2018 ni ifilọlẹ pataki nla naa waye ni ipinlẹ Eko, Naijiria.

Itan ati Aṣa Yoruba

Àkọlé fídíò,

"A gbúdọ̀ wẹ̀ ọmọ tuntun pẹ̀lú epo pupa, kàìnkàìn ìbílẹ̀ àti ọṣẹ dúdú'

Eto Idibo Naijiria

Àkọlé fídíò,

Ọ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé

Àkọlé fídíò,

Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba

Àkọlé fídíò,

2019 Elections: Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjíròrò Eko yóò bẹ̀rẹ̀

Àkọlé fídíò,

Iriwisi àwọn ará ìlú ṣe ọtọtọ lórí èsì ìdìbò Osun

Ọrọ to kan araalu

Lara awọn iroyin manigbagbẹ ti a ti sẹ ni yii nipa eto idibo gbogboogbo to waye lorilẹede Naijiria ni ọdun 2019, eto oṣelu ni Naijiria, asa, iroyin kayeefi to fi mọ iroyin awọn oṣere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Àkọlé fídíò,

Sotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn

Àkọlé fídíò,

Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú