Lassa fever: ìpínlẹ̀ Èkó kéde èèyàn kan pẹ̀lú ibà Lassa

Ibudo ayẹwo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iba Ọrẹrẹ, ti aye mọ si iba Lassa ti wọ ipinlẹ Eko bayii!

Kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo ṣalaye eyi ninu atẹjade kan lọjọru.

Ọjọgbọn Abayọmi ni ẹni naa ti wa labẹ itọju nileewosan nla fasiti ilu Eko, LUTH.

Amọṣa kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko ko ṣai fi awọn olugbe ipinlẹ naa lọkan balẹ pe ko si idi fun wọn lati foya nitoripe eto gbogbo ti to lati kapa iba naa to ba fẹ gbera sọ nibẹ.

O ni ileeṣẹ eto ilera ti n ṣe iwadii lori awọn eeyan ti ẹni to ko aarun naa ba da nnkan pọ lati mọ awọn to ṣeeṣe ko ti ko aarun ọhun lọwọ yii nipasẹ rẹ.

Bakan naa ni kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ Eko tun ke sawọn eeyan ipinlẹ Eko lati karamasiki ilera wọn ki wọn si yago fun ekute.

O ni awọn agbegbe ayẹwo iyasọtọ ti wa kaakiri lati tọju awọn eeyan to ba lugbadi aisan naa; ti oogun ati itọju to bagbamu pẹlu ilana agbaye si ti wa nikalẹ fun wọn.

Gẹgẹ bii iwadii ajọ to n ṣewadi ati igbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, eeyan eedẹgbẹta ati mọkanlelọgbọn ni wọn ti funra aisan iba Lassa si bayii lorilẹede Naijiria; mẹrinlelọgọrun ninu wọn ni wọn si ti fi idi rẹ mulẹ pe wọn ni aisan naa ti eeyan mẹfa si ti jade laye nipasẹ rẹ.