Tinubu ti ń gba orí ayélujára kan, àwọn aráàlú ń fèsì

Tinubu ti ń gba orí ayélujára kan, àwọn aráàlú ń fèsì

Lori ibo to n bọ lọna lọdun 2023, ṣe lo da bii pe la ni ọdun ti a n sọrọ rẹ yii nitori bi awọn ọmọ Naijiria tagba tọmọde ṣe ko si sisọrọ nipa rẹ.

Eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Naijiria, oloye Bode George ba BBC Yoruba sọrọ lori eyi.

Bakan naa, George ni gbogbo ara oun loun fi gbaruku ti eto ẹṣọ alaabo Amotekun tawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe agbekalẹ rẹ

Bode George ti oun naa fi igba kan ri jẹ gomina ologun ipinlẹ Eko sọ pe Amotekun yoo sọ aye dẹrun pẹlu eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria bayii.

O ṣalaye ẹṣọ Amotekun ni o le wa ojutu si eto aabo to mẹhẹ nitori awọn lo mọ awọn to wa lagbugbo wọn.

Bode George ni abosi lo wa n bẹ ti ipinlẹ Eko ko ba ṣe Amọtẹkun lẹyin ti gbogbo awọn gomina ipinlẹ Yoruba yoku ti fọwọ si agbekalẹ eto naa.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Bode George ni ipinlẹ Eko lo jẹ gbese ju lẹyin ijọba apapọ lorilẹede Naijiria