Lassa fever: Ìjọba Eko ní akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ebonyi tó wá kẹ́kọ́ ìmọ̀ òfin, ní wọ́n bá Lassa lára rẹ̀

Oluwadi ijinlẹ kan n n se iṣẹ iwadii rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọwọ ijọba ipinlẹ Eko ti tẹ awọn eeyan mẹtalelọgọta ti wọn ti ni ajọṣepọ pẹlu eeyan ti o ni aisan iba Lassa ni ipinlẹ Eko.

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun 2020 ni kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi gbe atẹjade kan sita pe ijọba ti ri eeyan kan, to ti ko aisan iba naa, ti wọn si ti fi onitọun si abẹ itọju makan nileewosan nla LUTH.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣọna feto ilera wa ṣalaye fawọn akọroyin lasiko to n ṣe ipade pẹlu wọn ni Ikẹja pe, awọn eeyan to ti ni ajọṣepọ pẹlu eeyan ọhun ni wọn ti fi si ahamọ fun itọju ati ayẹwo, lati rii pe wọn ko tii ko aisan naa.

Àkọlé àwòrán,

Dokita mẹjọ lo ti ba arun lassa lọ ni Naijiria

O ni akẹkọ fasiti ipinlẹ Ebonyi ni arakunrin ti wọn mu pẹlu arun iba Lassa ati pe, ibudo ikẹkọ agba nipa ofin, to wa ni ilu Eko lo wa lati gba imọ kun imọ nipa ẹkọ imọ ofin, ko to di pe aarẹ muu.

Kọmiṣọna feto ilera fi kun un pe, ileewosan ile ẹkọ naa to lọ lati ṣalaye pe iba n ṣe oun lo fi di ẹ mulẹ pe, nigba ti ko san lẹyin gbogbo itọju aisan iba gbogbo ti wọn fun un, ni wọn yẹ wo fun arun Lassa.

O wa rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Eko lati tete fi to ijọba leti, bi wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni to n ṣafihan awọn aisan iba ti ko fẹ gbọ ogun ati itọju, ki ijọba lee tete gbe wọn lọ fun ayẹwo ati itọju to ba yẹ.

Àkọlé fídíò,

Female Driver: Sokunbi ni obìnrin àwakọ̀ Dáńfó l‘Eko, tó ń lọ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíì

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Eko tun ya awọn nọmba ibanisọrọ kan silẹ fun ipe pajawiri lori aisan Lassa nipinlẹ naa.

Awọn nọmba ibanisọrọ naa ni 08023169485, 08033565529 ati 08052817243