Stellah Adadevoh: Ẹ̀bí dókítà náà ní ìfẹ́ Nàíjíríà ló ní tó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀

Dokita Ameyo Stellah Adadevoh

Oríṣun àwòrán, drasatrust

Awọn ẹbi oloogbe Dokita Stellah Adadevoh ti ni, inu awọn dun si igbesẹ ti ijọ́ba apapọ gbe lati fi opopona kan sọ ori dokita naa, lẹyin ọdun marun to doola orilẹede yii lọwọ ajakalẹ nla, to ṣeeṣe ki apa rẹ o maa ka.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Arabinrin Niniọla Williams ṣalaye pe, bi o tilẹ jẹ wi pe Dokita Adadevoh ko fi ẹmi rẹ lelẹ nitori ati gba ami ẹyẹ kankan, bikoṣe ifẹ nla to ni si orilẹede Naijiria, sibẹ inu awọn mọlẹbi ko ṣai dun si igbesẹ naa.

"Ọmọ orilẹede to nifẹ Naijiria tọkantọkan ni oloogbe Adadevoh, idi si niyi to fi ṣe ohun to ṣe"

Fun ọpọlọpọ ọmọ Naijiria to ranti ohun to ṣẹlẹ ni ọdun marun un sẹyin, wọn ko lee gbagbe orukọ Dokita Ameyo Stellah Adadevoh.

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun ti yoo si wa si iranti wọn ni ipa takuntakun ti arabinrin naa ko, lati rii daju pe aisan gbẹmigbẹmi nni, Ebola ko raye ṣọṣẹ lorilẹede Naijiria.

Bi kii ba ṣe ti Dokita yii ni, to fi tipa tikuuku de ọmọ orilẹede Liberia kan, Patrick Sawyer to ko arun naa wọ orilẹede Naijiria mọlẹ ni ileewosan rẹ, First Consultant Hospital, to wa nilu Eko, afaimọ ki ẹmi ti ko ba ba arun naa lọ nigba naa ma di ẹgbẹlẹgbẹ.

Lọna ati sọ orukọ akọni obinrin naa di manigbagbe, lọjọru ni ijọba apapọ fi orukọ Dokita Adadevoh sọ opopona kan ni olu ilu Naijiria, Abuja.

Oríṣun àwòrán, Others

Opopona naa, lo wa lagbegbe opopona Ahmadu Bello nitosi gbọngan ipade nla ti ileeṣẹ ọmọogun ofurufu ilẹ Naijiria, Nigeria Airforce Conference center.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2014 ni Dokita Adadevoh jade laye, lẹyin to ti ko arun Ebola naa lara Ọgbẹni Sawyer to wa sorilẹede Naijiria lati Liberia.

Ta ni Stella Adadevoh?

Oríṣun àwòrán, drasatrust

  • Ni ilu Eko ni wọn ti bi Stella ni ọdun 1956. Bi eeyan ba wo iran ti Stellah ti jade, a ri awọn akin bii alagba Hebert Macaulay, ọkan lara awọn to jijagbara fun orilẹede Naijiria.
  • Baba to bi Stella lọmọ gan an, Ọjọgbọn Babatunde Kwaku Adadevoh, ti figbakan ri jẹ ọga agba fun fasiti ilu Eko, ta si ri pe kii ṣe arosọ, ẹjẹ akin wa lara Dokita Stella ni.
  • Ilu Eko ni o ti ka iwe alakọbẹrẹ, ki o to kọri si ilu Ibadan fun eto ẹkọ girama rẹ.
  • O lọ si fasiti lati kẹkọ imọ nipa iṣegun oyinbo, to si lọ sisẹ ni ilu London nilẹ Gẹẹsi, ki o to pada silẹ wa, to si n siṣẹ ni ileewosan First Consultants Medical Center ni Eko fun ọdun mọkanlelogun, ki o to jade laye.
  • Ọdun 1986, iyẹn ọdun mẹtalelọgbọn sẹyin lo ṣegbeyawo, ti o si bi ọmọ kan.
  • Pẹlu opopona ti ijọba fi sọ ori rẹ yii, ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n sọrọ lori rẹ.

Ero ọmọ Naijiria nipa opopona tijọba fi sọri Adadevoh:

Awọn kan n woye pe ohun to loorin ju eyi lọ, bii ileewosan to ti ṣiṣẹ nigba aye rẹ, papakọ ofurufu, ibudokọ oju omi, tabi papa iṣere ati ileewosan apapọ orilẹede Naijiria, lo yẹ ki ijọba fi sọ ori dokita Adadevoh.

Bẹẹni awọn miran kan sara si ijọba fun igbesẹ naa ti wọn si tun n woye pe, o ku ni ibọn n ro, ki ijọba o ranti awọn oniṣẹ eto ilera miran to ku lasiko arun naa.