NURTW Oyo: Ìjọba Ọyọ ní awakọ̀ kankan kò ní tẹ̀lé àṣẹ yíyan iṣẹ́ lódì táwọn NURTW fi ń halẹ̀

Auxiliary atawọn alakoso gareji ọkọ yoku Image copyright Others

Ijọba ipinlẹ ọyọ ti fesi lori idunkoko ẹgbẹ awakọ ero NURTW lẹkun guusu Naijiria to n fẹ kijọba yi ipinnu rẹ pada lori yiyan awọn alakoso gareji ọkọ.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, akọwe feto iroyin fun gomina, Taiwo Adisa, to gbẹnu Seyi Makinde sọrọ salaye pe, awọn awakọ nipinlẹ Ọyọ nikan lo lasẹ lati sọrọ lori igbesẹ tijọba gbe lati yan awọn awọn adari ọkọ sawọn gareji gbogbo nipinlẹ naa.

Ijọba Ọyọ ni lọdọ awọn, ko sẹni to mọ okolo awọn ẹgbẹ NURTW lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lọyọ, tori wọn ko fi orukọ silẹ lọdọ awọn, oye ohun to si n waye nipinlẹ naa ko ye wọn to.

Image copyright Others

Ijọba ni ohun ti ko kan awọn asaaju ẹgbẹ awakọ ero naa ni wọn n dasi, bẹẹ si ni igbesẹ ijọba Ọyọ lati maa gba owo ni ẹẹkan lojumọ lo dun mọ awọn awakọ yika ipinlẹ naa ninu, lodi si ohun to n waye tẹlẹ.

"Tẹlẹtẹlẹ, awọn awakọ ero nipinlẹ Ọyọ lee sanwo fun irinajo kan ni ọna meji, orita bii mẹta si ni wọn yoo ti sanwo ita naa. Apo awọn eeyan kan si ni owo naa n lọ, eyi ti ko dara to."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe, igbesẹ tijọba gbe naa lo n mu ominira ba awọn awakọ gan ni, owo ẹẹkan pere ti wọn ba san wa lati aarọ titi di alẹ, pẹlu afikun pe awọn to n dunkoko mọ ijọba ko mọ ohun ti wọn n sọ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemale Driver: Sokunbi ni obìnrin àwakọ̀ Dáńfó l‘Eko, tó ń lọ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíì

"Agbeyẹwo tijọba n se yoo mu ilọsiwaju ba awọn awakọ, ti ijọba yoo si nawo fun atunse awọn gareji ọkọ wa, ti iyatọ yoo si ba wọn laarin ọdun kan, yatọ si bi awọn eeyan kan se maa n da owo gareji si apo ara wọn.".

Nigba to n salaye lori idunkooko pe awọn asaaju ọlọkọ naa yoo pasẹ fawọn awakọ lati dasẹ silẹ, ijọba Ọyọ ni ala ti ko lee sẹ ni idunkooko naa, ko si si awakọ kankan nipinlẹ Ọyọ ti yoo tẹle asẹ awọn adari ẹgbẹ NURTW naa.

"Igbesẹ ijọba yoo tubọ mu ki owo pọ ni apo awakọ ero kọọkan ni, ti yoo si mu si gba owo kuro lọwọ awọn asaaju ẹgbẹ. Ti igbesẹ naa ko ba si tẹ awọn asaaju ẹgbẹ lọrun, ọkọ tiwọn nikan, to jẹ ẹtahoro ni wọn yoo gbe kuro loju popo, tori ko si awakọ to ya owo ra ọkọ ara rẹ, ti yoo gbọrọ si wọn lẹnu."

Image copyright Others

Ijọba Ọyọ ni oun ko di isẹ awakọ lọwọ rara, o si rọ awọn awakọ ero lati maa ba isẹ wọn lọ, ki wọn si gbọn eti wọn si ohun ti awọn olori ẹgbẹ to n gba owo lọwọ wọn n sọ.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹgbẹ NURTW lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ni oun ko faramọ iyansipo alaga tẹlẹ fẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, Mukaila Lamidi, ti gbogbo eeyan mọ si Auviliary gẹgẹ bii oludari awọn alakoso gareji tijọba sẹsẹ yan.

Image copyright Seyi Makinde

Awọn asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero naa, ninu eyi taa ti ri MC Oluomo tun n dunkooko pe awọn yoo ni kawọn awakọ ero dasẹ tilẹ tijọba Ọyọ ko ba tẹle ohun tawọn n fẹ laarin ọjọ meje.