Seyi Makinde: Ìjọba Ọyọ ṣetán láti pèsè káàdì ìdánimọ̀ fáwọn ọlọ́kadà

Awọn ọlọkada

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti setan lati gunle ipese kaadi idanimọ fawọn ọlọkada jakejado ipinlẹ naa lọna ati dena iwa ọdaran ati apsju awọn ọlọkada nipinlẹ naa.

Bakan naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti pasẹ pe ki adinku ba igba naira owo ojumọ ti awọn ọlọkada yẹ ko san si ọgọrun naira.

Kọmisana feto isẹ ode, ipese awọn ohun eelo amayedẹrun ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ọyọ, Raphael Afọnja lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Bakan naa lo fikun pe gomina Makinde ko fẹ di kun ajaga awọn araalu lo se mu adinku ba owo tawọn ọlọkada n san, ti yoo si tun pese kaadi idanimọ fun gbogbo ojulowo ọlọkada pata to n sisẹ aje nipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi Afọnja ti wi, ijọba fẹ gbe igbesẹ naa ka lee mọ ojulowo ọlọkada yatọ si awọn to jẹ asawọ laarin wọn nitori gbogbo alaamu lo da ikun delẹ, a ko mọ eyi ti inu n run ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

"Ta ba wo bi ijọba se fofin de awọn ọlọkada ati oni kẹkẹ Maruwa nipinlẹ Eko, ọpọ wọn lo ya wa sipinlẹ Ọyọ, a si ti pinnu pe a seto kaadi idanimọ fawọn ọlọkada naa, ka lee mọ ẹni ninu ẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni kọmisana fun isẹ ode fikun pe ijọba Ọyọ yoo sisẹ pọ nifọwọkọwọ pẹlu awọn osisẹ ajọ ẹsọ oju popo FRSC pẹlu awọn ẹka to n pawo wọle labẹle lati se akojọpọ orukọ nipa awọn ọlọkada ero ati aladani, eyi ti yoo tun wulo fun awọn agbofinro pẹlu.

Afọnja ni "Asigbọ kan lo waye laarin wa pẹlu ajọ to n pawo wọle ati ileesẹ eto isuna, ohun ta gbọ ni pe igba naira lawọn ọlọkada yoo maa san lojumọ, nigba ti gomina Makinde gbọ, ko ba lara mu rara, to si ni ka mu adinku ba owo ojumọ ti awọn ọlọkada n san lati igba si ọgọrun naira."

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Kọmisana ni gareji ọkọ kọọkan ni wọn yoo ti maa gba owo yii bẹrẹ lati oni, ọjọ Ẹti lọ, to si n rọ awọn ọlọkada lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ọyọ.