Oluwo: Ó dàbí ẹni pé ọ̀tá pọ̀ fún mi, inú wọn kò dùn sí bí mo ṣe ń ṣakọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captioniyonipo

Oluwo tilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti fesi lori ipinnu igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun to ni ko lọ rọọkun nile fun osu mẹfa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwo ni lootọ ni awọn se ipade lọbalọba lootọ ti Ọọni ko si ni asẹ lati ni ki oun lọ rọọkun nile na.

O ni gomina ipinlẹ Ọsun nikan lo ni asẹ lati ni ki oun lọ rọọkun nile na, to si dabi ẹnipe wọn ti ni nkan ninu si oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"O dabi ẹni pe inu wọn ko dun bi mo se maa n sakọ, ti wọn si n binu mi. Gbogbo wọn ni wọn kan oro mi sinu, o si dabi ẹni pe ọta pọ, Ọlọrun yoo si gbe mi jẹri wọn."

Image copyright Instagram

Nigba to n sọrọ lori bi wọn se ni o yaju si Alaafin ati Ọọni, Oluwo ni oun ko gba ade ni Ọyọ, oun si ni oun lasẹ lati fi ọba miran jẹ nilẹ Iwo, kii se Alaafin, gẹgẹ bo se waye ni Ikoyi.

Image copyright Oluwo

"Ile ifẹ ni mo ti gbade lọdọ iya mi, tori ọmọ alade ni mi nile Ifẹ, emi ko gba ade ni Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ni Alaafin wa, ko si lee maa gbe ade le Onikoyi to wa labẹ mi lori. Alaafin sọrọ si mi tori pe n ko jẹ ko gbe ade le Onikoyi lori, amọ ibi to ba kan onikaluku ni ko duro si bii ọba."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Oluwo ni oun si ni Ọba alade nilẹ Iwo, Oluwo ti Iwo, Alase lori orisa, ọba miran ko si lee ni ki oun lọ rọọkun nile na, wọn kan le ni ki oun ma wa si ipade wọn mọ ni.

Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l'Ọ́sun ní kí Oluwo lọ rọ́ọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti kede pe igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun ti ni ki Oluwo tilu Iwo, Aba Abdulrasheed Akanbi lọ rọọkun nile fun osu mẹfa gbako.

Image copyright Oluwo

Igbimọ kan ti igbimọ lọbalọba naa gbe kalẹ, eyi ti Ọrangun ile Ila, Ọba Wahab Adedọtun ko sodi, lati sewadi awọn isẹlẹ to nii se pẹlu Oluwo, gbe abọ wọn kalẹ lọjọ Ẹti.

Lẹyin abọ igbimọ naa, ni igbimọ lọbalọba ọhun ba pe ipade pajawiri, eyi to waye nibujoko ijọba ipinlẹ Ọsun to wa ni Abẹrẹ.

Ipade naa, ti Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi lewaju rẹ, wa fohun sọkan pe ki Oluwo lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa.

Image copyright Ọba Dikrulahi Ọlaleke Akinrọpo, Ọlabiran Kẹta.

Igbesẹ yii si lo waye lẹyin ọsẹ kan pere ti Oluwo lu Agbowu tilu Ọgbaagba nibi ipade alaafia kan ti igbakeji sga agba ọlspa pe nilu Osogbo.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade pajawiri naa, Ọrangun Ile Ila ni asẹ ti igbimọ naa pa pe ki Oluwo lọ rọọkun nile na ko ni ohunkohun se pẹlu ija to waye laarin rẹ ati Oluwo.

Amọ o ni wọn se ipinnu ọhun lẹyin iwadi wọn nipa isesi Oluwo si awọn ọba alaye yoku nilẹ Yoruba.

Image copyright Oluwo

Ọrangun ni Oluwo ti yaju tẹlẹ si Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyemi Kẹta ati Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi.