Fayose: APC Ekiti ní àwọn olóṣèlú tó ti fìdírẹmi kò le è ráyè láàrin àwọn

Ayodele Fayose, gomina ana ni ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Ayodele fayose

Ẹni ba mọ gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele ọmọ Fayoṣe, ko yara sọ fun un pe bo ba n gbero ati dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ yii, ko tun ero naa ro o, nitori ko daju pe ọna wa nibẹ fun un.

Gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ekiti ṣe sọ, bi Fayoṣe ba n gbero ati fi ẹgbẹ oṣelu PDP to wa silẹ, wa dara pọ mọ APC, awọn ko ni tẹwọ gba a.

Ọpọ eeyan ni yoo wi pe, awọn ko ri idi ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa yoo fi gbe igbesẹ ati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ si APC, paapaa bi o ṣe jẹ wi pe odu ni Fayoṣe jẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako.

Oríṣun àwòrán, Ttribune online

Bẹẹ ba gbagbe, Fayose lo n fi gbogbo igba gbe ohun dide tako Aarẹ Buhari pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn APC, eyi si lo mu ki awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn fẹ ki o mọ pe, aye rẹ ko ṣi silẹ laarin awọn.

Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ade Ajayi ṣalaye nilu Ado Ekiti pe, Ẹgbẹ oṣelu naa ko si fun awọn oloṣelu to ti jakulẹ pẹlu afikun pe, ilẹkun ẹgbẹ oṣelu APC ko si silẹ fun Fayose.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Gẹgẹbi ọrọ rẹ, " Fayoṣe ko ni amuyẹ lati di ọmọ ẹgbẹ APC ni ipinlẹ naa"