Electricity Tariffs: DISCOs ní oko gbèsè ni ìjọba ń rán àwọn pẹ̀lú owó tó ń kéde fún iná

Opo ina manamana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adari ajọ to n ri si itankalẹ ina ọba ní Naijiria, TCN, Usman Mohammed mu iroyin kan tọ araalu wa lọjọbọ pe, laipẹ laijina, iye ti wọn n ta ina ọba lorilẹede Naijiria yoo gbẹnu soke sii.

O ni ko si idi meji fun eyi naa ju pe, ki araalu lee tubọ maa janfani to sodo sinu ilana sisọ ipese ina di ti aladani.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ṣa, ibeere tawọn eeyan wa n beere ni pe, ṣe iyatọ yoo de ba ijafafa ipese ina manamana faraalu bi owo naa ba goke, awọn agba bi eeyan ba fowo ra ooyi, o yẹ ko kọọ loju.

Nigba ti o n ba BBC News sọrọ lori iroyin naa, agbẹnusọ fun awọn ileeṣẹ to n pin ina manamana lorilẹede Naijiria, DISCOs, Amofin Sunday Ọduntan ṣalaye pe, ohun to sọnu lẹka ipese ina ọba kọja ikede afikun owo ina ti alaga ajọ TCN ṣe naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọfin Ọduntan ni, awọn igbesẹ jọmọ o ṣowo, maa jọmọ o kowo dele ti ijọba apapọ n gbe kalẹ ni ẹka naa, n ṣe ọpọ akoba fun bi araalu ṣe n gbadun ina si.

Ninu ọrọ rẹ o ni, bi iye ti ijọba fẹ kede ba kere si owo ti awọn ileeṣẹ apinna, DISCOs n san lati fi ra ina lọwọ ijọba, ofo ọjọ keji ọja ni igbesẹ naa yoo jasi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbẹnusọ fun awọn ileeṣẹ to n pin ina manamana, DISCOs naa ṣalaye pe, ọgọrin naira o le kọbọ diẹ ni awọn ileeṣẹ DISCOs n san lati ra ina lọdọ ileeṣẹ itankalẹ ina ọba, TCN.

Sugbọn, o ni ijọba fi ofin kan an nipa fun wọn lati maa ta ina bẹẹ ni naira mọkanlelọgbọn ati kọbọ diẹ, eyi to tumọ si pe adanu nla lawọn ileeṣẹ apinna DISCOs n pa lori owo wọn.

"O di igba ti ijọba ba to jẹ ki iye owo ti eto karakata n gbe jade loju ọja, ki ọrọ to lee yanju lẹka ipinsẹ́ ina ọba lorilẹede Naijiria.'

Oríṣun àwòrán, Others

Ọduntan ni oju opo ina pinpin jakejado Naijiria ti di alapa, eleyi ti ko lee gbe agbara ina pupọ, leyi to ni o n fa bi ina manamana ṣe maa n ku pii jakejado Naijiria.

O ni bi orilẹede Naijiria ṣe tobi to, ko si igba kankan ti ina ọba ti orilẹede yii n gbe jade de ẹgbẹrun mẹfa kilowaati, gẹgẹ bi ijọba ṣe maa n pariwo kiri lọpọ igba.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

"Agbara ina to ga ju ti orilẹede Naijiria de ri jẹ ẹgbẹrun marun abọ o le diẹ mẹgawaati ina, eyi ko si ju aarin wakati mẹrinlelogun lọ ti o tun fi pada si ẹsẹ aarọ rẹ"