Boko Haram: CAN àti àwọn ará Chibok ní kò sí orílẹ̀èdè tó yege nínú yíyí ọkàn aṣẹ̀rùbálú padà

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, @ElvisChinedu12

Ile igbimọ aṣofin nilu Abuja ti gunle abadofin ti yoo ṣedasilẹ ileeṣẹ ijọba, ti yoo ma ṣetọju awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to ba ronupiwada.

Abadofin ọhun ni Sẹnatọ to n ṣoju Ila-oorun ipinlẹ Yobe, to tun jẹ gomina ana nipinlẹ ọhun, Ibrahim Gaidam n ṣagbatẹru rẹ.

Gẹgẹ bi agbekalẹ abadofin naa ṣe sọ, ileeṣẹ ọhun yoo pese anfani fun awọn agbesunmọmi to ba jọwọ ohun ija wọn, lati lọ si ile iwe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin eyi, yoo ṣe atunkọ ohun ti wọn gbagbọ, iyipada ọkan wọn, ti yoo si tun da awọn eeyan naa pada si awujọ gẹgẹ bi ẹni to ti ni iyipada ọkan ati ẹdun tuntun.

Ko tan sibẹ, ileeṣẹ naa yoo tun kọ awọn eeyan naa ni iṣẹ ọwọ bii gbẹnagbẹna, iṣe amọkoko, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Igbimọ to ga julọ fun ọrọ ẹsin Musulumi, eyi ni Supreme Council for Islamic Affairs ti ṣe atilẹyin fun abadofin naa.

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Ṣugbọn lẹyin wakati diẹ ti abadofin naa kọja kika akọkọ, ni awọn olugbe ilu Chibok, ti Boko Haram ṣakọlu si lọdun 2014 ati CAN tako abadofin naa.

Bẹẹ naa ni adari ajọ ọmọlẹyin Kristi, CAN lori ọrọ ofin, Kwamkar Samuel sọ fun awọn akọroyin pe, oun ko tii ri orilẹ-ede kankan lagbaye to ṣaṣeyọri ninu yiyi ọkan ẹgbẹ aṣẹrubalu pada.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá

Yatọ si ẹgbẹ CAN ati awọn ara ilu Chibok, ogunlọgọ awọn Naijiria lo n bu ẹnu ẹtẹ lu awọn asofin naa pe, abadofin ọhun kii ṣe ọna abayọ si ọrọ ikọ Boko Haram.

Agbẹnusọ fun ilu Chibok ni tirẹ sọ pe, abadofin ọhun jẹ ohun ti ko ni ọgbọn ninu.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla Oṣu Kẹrin ọdun 2014 ni ikọ Boko Haram ṣakọlu si ilu Chibok, to si ji awọn ọdọbinrin to le ni igba gbe lọ.

Àkọlé fídíò,

Ìlú Eko ló jẹ gbèsè jù ní Nàìjíríà lẹ́yìn ìjọba àpapọ̀