Yollywood: Bákan náà ni àwòrán Sikiratu Sindodo tó ń ṣọjọ́ ìbi, gba orí ayélujára

Toyin Abraham ọkọ rẹ̀ àti Ire ní London

Oríṣun àwòrán, ourlovefrotoyinabraham

Eyi ni agbeyẹwo awọn nnkan tawọn oṣere tiata Yoruba, Yollywood ṣe lọsẹ yii.

Toyin Abraham

Awọn ololufẹ oṣere Toyin Abraham ati ọkọ rẹ Kola Ajeyemi fi oriṣiiriṣii fọto awọn mejeeji pẹlu ọmọ wọn, Ire, soju opo Instagram, nibi ti wọn ti di kaka di kuuku niluu London.

Awọn olololufẹ wọn ni, ẹni ti ko ba ti ba idile Toyin Abraham pade, ko gbiyanju lati ṣe bẹẹ nitori idile ti o dara ni.

Wọn ni ifẹ awọn si Toyin ati Kola ko le tan laelae, nitori ọmọluabi ni wọn.

Sindodotayo

Inu ẹni kii dun ki a pa mọ ra. Bẹẹ gẹgẹ lọrọ ri pẹlu oṣere tiata, Tayo Odueke ti ọpọ mọ si Sikiratu Sindodo, to n ṣopẹ fun Eleduwa to mu ri ọjọ ibi rẹ mii.

Ọ sọ loju opo Instagram rẹ pe ẹrin keke lo gba ẹni oun lonii ọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ ibi oun.

Tayo sọ pe oun ko le tori bi ilu ṣe ri ki oun maa dunnu lọjọ ibi oun, bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun tubọ maa fi ere si iṣẹ ọwọ oun.

Odunlade Adekola

Gbajugbaja oṣere Odunlade Adekola fi fọto ara rẹ ati ti olootu rẹ, Mercy Aigbe sori oju opo Instagram nibi tawọn mejeeji ti rẹrin muṣẹ.

Odunlade sọ pe Mercy ni olootu ere tiata ti oun kopa ninu rẹ, eyi ti akọle rẹ n jẹ ''DARA.''

Femi Adebayo Salami

Aṣọ to gbajugbaja ni oṣere Femi Adebayo Salami fi dawọ idunnu opin ọsẹ.

Awọ pupa ni aṣọ ọhun pẹlu fila pipa naa lori rẹ, bata alawọ funfun ni Femi Adebayo fi wọ si ori aṣọ naa.

O sọ loju opo Instagram rẹ pe ara ọjọ Ẹti ọsẹ yii ni imura oun duro fun eyi to pe ni ''Friday swag.''