Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Ara ko ni tan nile alara ni Yoruba n sọ, airin jinna si ni airi abuke ọkẹrẹ.

Ina ti ọpọ eeyan maa n sa fun tori ọsẹ to lee ni se ni ọkunrin kan to n jẹ Timi, n jẹ bii ounjẹ, o fi n pa ara, to si tun n fi sere.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọkunrin naa ti inagijẹ rẹ tun n jẹ Azonto fikun pe oun lee fi omi lasan tan ina, bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan gba pe ina ati omi kii se ọrẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Azonto ni lasiko ti oun n sere itage ni oun kọ isẹ naa nipinlẹ Ogun, ti gbogbo eeyan si maa n pe oun ni Sango lai wa lati idile onisango tabi jẹ ọmọ ilẹ Yoruba.

Timi wa rọ yin kẹ mase fi ina sere nitori a kii dagba kọja ohun ti a ko ba mọ, ina si lewu.

Credit Joshua Akinyemi