Abacha Loot: Amẹ́ríkà ní gómìnà Kebbi ló bá Abacha kó ọ̀pọ̀ bílíọnù dọ́là wá, tó sì lo oṣù mẹ́fà ní àhámọ́ òun

Muhammadu Buhari n fa ọwọ Atiku Bagudu soke bii oludije gomina APC nipinlẹ Kebbi

Oríṣun àwòrán, @FRNcitizens

Laipẹ yii ni iroyin kan awọn ọmọ Naijiria pe ijọba ilẹ Amẹrika tun ti sawari owo kan ti olori tẹlẹ fun ijọba ologun ni Naijiria, oloogbe ọgagun Sani Abacha ko pamọ sorilẹede naa, ti wọn si setan lati daa pada fun wa.

Inu gbogbo ọmọ ilẹ yii lo n dun, taa si n fo fayọ pe owo tun de amọ iroyin to wa gbalẹ kan bayi ni pe ileesẹ eleto idajọ lorilẹ ede Amẹrika ti n dena mọ bi owo yii yoo se tẹ ijọba Naijiria lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba to jẹ pe ti ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ, ohun ti wọn lo fa sababi ni bi ijọba ilẹ Naijiria se n gbero lati yọ miliọnu lọna ọgọrun ninu owo naa fun gomina Atiku Bagudu, tipinlẹ Bauchi.

Ninu iwe ipẹjọ kan ti ẹka eto idajọ gbe siwaju ileẹjọ District Colombia ti Washinton, ni akara ọrọ naa ti tu sepo, gẹgẹ bi iwe iroyin ilẹ Amẹrika kan ti gbe jade, ti ijọba apapọ ko si ti fesi le lori.

Oríṣun àwòrán, @cbngov_akin1

Ileesẹ ilẹ Amẹrika naa ni, ijọba orilẹede Naijiria lo n dina gbogbo igbiyanju wọn lati ri owo Abacha gba pada, eyi ti wọn tọpasẹ rẹ de ọdọ alaga ẹgbẹ awọn gomina fẹgbẹ oselu APC, tii tun se gomina ipinlẹ Bauchi ọhun.

Wọn ni Bagudu, tii se korikosun Buhari ati eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC, nijọba ilẹ Amẹrika ti fẹsun kan saaju pe oun lo seranwọ fun Abacha lati fẹyin pọn aimọye biliọnu dọla jade kuro ni Naijiria nidaji saa ọdun 90s.

Oríṣun àwòrán, @AnasAda04084492

Iwe naa ni osu mẹfa gbako ni Bagudu lo ni atimọle awọn nilu Texas nigba ti wọn fẹ di lapanyaka lọ si erekusu kan ni Jersey amọ se lo yara tete gba lati da miliọnu lọna mẹtalelọgọjọ dọla pada si Naijiria, ti wọn si fa le ilẹ Naijiria lọwọ pe ko lọ foju wina ẹsun kiko owo tuulu lọ soke okun.

Amẹrika ni fun iyalẹnu, bi Bagudu se de silẹ Naijiria, ni wọn wẹ ẹ mọ kuro ninu awọn ẹsun naa, to si n du ipo oselu lọ, lati ile asofin agba de ipo gomina, to si n gbadun ofin mafọwọ kan mi lọ.

Bakan naa ni ileesẹ eto idajọ Amẹrika fikun pe ijọba Naijiria ni ko jẹ ki aayan ilẹ Amẹrika so eso rere lati gba owo to tọpasẹ rẹ de ọdọ Bagudu pada, o ni ijọba Buhari ni adehun ọlọdun mẹtadinlogun ti wa nilẹ, eyi to fun Bagudu lẹtọ si owo naa, ti ko si ni jẹ kijọba seranwọ fun Amẹrika lati gba owo ọhun.

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Iwe naa wa n salaye pe awọn isẹlẹ yii lee sokunfa ede aiyede ti yoo sediwọ fun ifọwọsowọpọ laarin Naijiria ati Amẹrika lati gba owo ti Abacha ko wa soke okun, eyi ti ajọ Transpartency International ni o to biliọnu marun dọla.