Amotekun: Miyetti Allah ní òun yóò péjú síbi ìpàdé ìta gbangba lọ́jọ́ Ajé láti sọ tẹnu òun

Amotekun

Bi wọn ba n ke gbe gbe gbe, ti a ko ba bawọn gbe, afaimọ ki wọn ma gbe si ẹyinkule wa.

Idi ree ti ẹgbẹ Miyetti Allah to jẹ awọn olusin maalu lorilẹede Naijiria, ti wọn jẹ ẹya Fulani, naa fi n kede faraye pe awọn ko ni gbẹyin nibi ipade ita gbangba lori agbekalẹ ẹsẹ alaabo Amotekun ti yoo waye lọjọ Aje.

Miyetti Allah ni awọn fẹ lọ sibi ipade ita gbangba ọhun lati fi ero awọn han lori ifilọlẹ ikọ alaabo ọhun lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @tosinsammy_s

Alaga ẹgbẹ Miyetti Allah nipinlẹ Ogun, Abdulmumin Ibrahim sọ fawọn akọroyin pe ko yẹ ko jẹ ẹya Yoruba nikan ni yoo wa ninu ẹsẹ alaabo Amotẹkun niwọn igba ti yoo dojukọ aawọ to maa n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Ibrahim ni awọn ko fẹ ki wọn sọ ẹsọ alaabo Amotekun di ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Oodua, OPC, o si yẹ ki wọn gba awọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti Allah sinu ikọ Amọtẹkun naa, ko lee fidi mulẹ bo se yẹ.

Ko tan sibẹ, akẹẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Ondo, Alhaji Garuba Bello naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti Allah yoo bawọn peju sibi ipade gbangba lori Amotekun lọjọ Aje, to si fikun pe oun tijọba ba ni ki awọn se, lawọn yoo se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba si gbagbe, ẹgbẹ Miyetti Allah yi lo ti n tako agbekalẹ eto alaabo Amotekun latẹyinwa, ti wọn si ni afojusun eto naa ni lati le ẹya Fulani jinna rere si ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Amọ awọn gomina to wa nilẹ Yoruba ti wa sọ fawọn Fulani pe ibẹru wọn yii ko lẹsẹ nilẹ, ko si tọ, bẹẹ ni ko pọn dandan.