Mother Language Day: Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè l‘Eko ṣe káre sí BBC Yorùbá fún àgbéga àṣà

Ami ẹyẹ ti BBC Yoruba gba

Yinni Yinni, kẹni lee se omiran ni, bẹẹ si ni ku isẹ lo n mu ki ori onisẹ ya.

Eyi lo mu ki ẹgbẹ Akọmọlede ati asa Yoruba, ẹka tipinlẹ Eko fi n fẹmi imoore wọn han si ileesẹ akọroyin BBC Yoruba fun isẹ takuntakun ti wọn n se lati se agbega asa, ede isesi ati awọn ohun ajogunba iran Yoruba.

Ẹgbẹ Akọmọlede naa fi ami ẹyẹ da BBC Yoruba lọla lasiko ayẹyẹ aadọta ọdun ti wọn da silẹ, eyi ti wọn fi sọri ayajọ agbelarugẹ ede abinibi to waye lọjọ Ẹti.

Ileẹkọ girama Ikeja, to wa ni Bọlade-Osodi nilu Eko si ni ayẹyẹ naa ti waye, akori ajọdun naa si ni ‘Isamulo ede abinibi fun idagbasoke, ibomirin, alaafia ati ibalaja.

Nigba to n ki awọn alejo to peju sibi ayẹyẹ ọhun kaabọ, alaga ẹgbẹ Akọmọlede ati Asa nipinlẹ Eko, Zainab Ọlaide aya Ọlaitan mọ riri ipa takuntakun tijọba ipinlẹ Eko n ko si idagbasoke eto ẹkọ.

Bakan naa, aya Ọlaitan tun dupẹ lọwọ awọn akọroyin lọkanojọkan, to fi mọ ileesẹ BBC Yoruba, lori ilakaka wọn lati ri pe ede Yoruba tẹ siwaju, to si gba adura pe ọba oke yoo pin wọn lere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A mọ riri ileesẹ BBC News Yoruba fun ipolongo ede, aṣa ati ise Yoruba. A si n fi asiko yii dupẹ lọwọ yin fun isẹ takuntakun alailẹgbẹ ti ileesẹ yin n se laarin wa."

Nigba to n tẹwọgba ami ẹyẹ naa lorukọ ileesẹ iroyin BBC Yoruba ati BBC lagbaye, Olootu ileesẹ iroyin BBC Yoruba, Ọgbẹni Temidayọ Ọlọfinsawo mẹnuba ọpọ isẹ ribiribi tileesẹ wa n se nidi agbega asa ati ede Yoruba, eyi ti ko fi ni jẹ ki awọn ohun ajogunba wa parun.

Ọlọfinsawo ni " Ohun itiju gbaa ni ki ọmọ ilẹ Kaarọ ooojire ma lee sọ ede Yoruba to dangajia lẹnu. Kekere si lo yẹ ka ti pẹkan iroko awọn ọmọ wa, nipa sisọ ede abinibi si wọn ninu ile nitori ọpọ adanu lo wa lọjọ iwaju, ti ọmọ ko ba mọ ede Yoruba sọ."

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Ọpọ awọn eeyan jankajankan miran to n se agbeaga fun asa ati ede ilẹ wa ni wsn tun fun lami ẹyẹ nibi ayẹyẹ naa, to fi mọ afihan awọn ohun isẹmbaye wa, to jẹ manigbagbe.

Àkọlé fídíò,

BBC Yorùbá: Temidayọ Ọlọfinsawo ní kò rọrùn láti darí òṣìṣẹ́ ọlọ́pọlọ pípé