Oluwo: Ọ̀ràngún ní táwọn kò bá ní kí Oluwo sinmi nílé, kò ní ṣíwọ́ ìwà àbùkù tó ń ṣe

Àkọlé fídíò,

Orangun ṣàlàyé ìdádúró Oluwo ní ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba

Ọrọ ti n foju han bayii lori idi ti igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun fi pasẹ fun Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulroshid Adewale Akanbi, Telu Kinni, lati lọ sinmi nile fun osu mẹfa gbako.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọrangun ile Ila, Ọba Wahab Kayode Oyedọtun, Bibire Kinni salaye pe, ko si ẹni to kanro Oluwo sinu tabi korira rẹ tori pe o n se akọ, asa ilẹ wa naa lo n gbe ga, eyi si kọ lo jẹ kawọn juwe ọna ile fun.

Ọba Oyedọtun ni, Ọọni tilu Ile Ifẹ lo pe ipade pajawiri awọn lọbalọba pe kawọn wa jiroro, lori ohun to lee faa aawọ laarin Oluwo ati Agbowu, gẹgẹ bo se waye lọsẹ kan sẹyin, bẹẹ si ni ọjọ naa kii se ọjọ ipade awọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram

O ni ipade naa kun gan, ti awọn ọba to wa nibẹ si le ni ọgọrin, nigba ti Ọọni si n fi ẹdun ọkan rẹ han lori isẹlẹ naa, lo ti salaye pe oun ko si nile, Abuja ni oun wa, amọ oun sare wale ni, inu awọn ọba Arẹwa ati ila oorun ilẹ yii ko dun sawọn ni Ọsun, ti wọn si n rọ oun lati wa nkan se si bi ọba se n na ọba nilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Ọrangun ile Ila

Kabiyesi ni awọn pe igbakeji ọga agba ọlọpa, AIG, ni Ọsun pẹlu awọn lọgalọga osisẹ ọba miran sibi ipade yii, Agbowu si lo kọkọ sọrọ nipa bi Oluwo se na oun lalubolẹ ni iwaju ọga ọlọpa, to si fi ọrun rẹ ti wọn we bandeji mọ, han awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A ni ki Oluwo naa ba wa sọrọ amọ ohun ta ri dimu ninu ọrọ rẹ ni pe, oun ko na Agbowu, oun kan kilọ fun pe ko ma na ọpa ọwọ rẹ si oun mọ ni. O ni wọn n ta ilẹ Iwo, oun si ni oun fi awọn ọba abẹ oun sipo, koda awọn ọba to wa laarin oun ati Agbowu lọjọ naa to mẹrin, ti wọn ko si jẹ ki ọwọ oun to o."

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

iyonipo

"Sugbọn sibẹ Agbowu ni Oluwo na oun lalubolẹ, koda o ni igbakeji ọga agba ọlọpa lo wa gbe Oluwo dide lori oun, nigba ta si bi AIG, o ni oun ko fi ọwọ kan wọn, amọ ẹri to daju han pe lootọ ni Oluwo na Agbowu."

Ọrangun fikun pe, ti isẹlẹ naa ko ba tiẹ to awọn loju, amọ mọ igba ti Oluwo lọ fi abuku kan Alake nilu Abẹokuta, nibi eto kan ti onitọun pe si, to si ni ori aga ti wọn pese silẹ fun Ọọni, ni oun fẹ joko le lori nitori Ọọni ko ju oun lọ.

Oríṣun àwòrán, Oluwo

"A ri igba to tabuku Alaafin naa nipinlẹ Ọsun, a si mọ bo se maa n wọ Ọọni nilẹ loju wa lasiko ipade awa ọba, awọn eleyi si ti to lati sọ fun Oluwo pe ko lọ sinmi laarin wa, to ba tiẹ ni oun ko na Agbowu, ta si mọ pe eleyi kii se ootọ, a kan bẹ Agbowu ni pe ko mu suuru, ara iya ọba naa niyẹn. Ọlọrun ko si ni fi iya jẹ."

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

"Igba ta wa wo ọrọ yii si ọtun ati osi, a ri pe ta ba fun Oluwo ni ewe dẹkun, o le e ma siwọ ohun to n se yii, ijoko wa ko si fun wa lasẹ lati yọ ọba kankan, awa ko tiẹ fẹ ki wọn yọ ọba, tori idile to ti wa ati ati abuku to maa jẹ fun ori ade kaakiri nilẹ Yoruba."

Ọba Oyedọtun ni, awọn lee kilọ fun ara awọn, lawọn se ni ki Oluwo lọ sinmi laarin awọn naa ninu igbimọ lọbalọba fun osu mẹfa, awọn ko si yọ Oluwo gẹgẹ bii ọba tori ileẹjọ nikan lo lasẹ lati yọ ọba.

"Lasiko ti Oluwo ba fi n sinmi nile, a sọ fun pe ko gbọdọ ba awọn akọroyin sọrọ, tori to ba sọrọ, yoo tun maa ba ẹjọ ara rẹ jẹ ni, ko gbọdọ kọrin owe abi eebu, o gbọdọ maa lọ jẹẹjẹ, ko si maa ba isẹ rẹ lọ, amọ ko gbọdọ wa si ipade awa lọbalọba tipinlẹ Ọsun."

Oríṣun àwòrán, @asiwaju_ayobami

O ni lẹyin eyi, awọn maa se atunse laarin awọn ọba ti Oluwo ti huwa abuku si kaakiri Naijiria, awọn yoo lọ ri wọn, pe ki wọn fiye denu, Oluwo naa ko si ni se bẹẹ mọ.

Kabiyesi ni inu awọn lọbalọba ni Ọsun ko dun rara, paapa awọn ọba to wa lati ilẹ Iwo ati ilu Ọgbaagba, awọn kan n fi ọgbọn-gbọn tu wọn ninu ni, ti Oluwo ba si dakẹ, to rọra n ba isẹ rẹ lọ, awọn yoo ri aaye tọwọbọ ọrọ naa, ti alaafia yoo fi jọba laarin wọn.

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Nigba to n fesi lori ọrọ ti Oluwo sọ pe, awọn ọba kan lo kan oro oun sinu, ti wọn n binu oun nitori pe oun n sakọ, Ọrangun ni se Oluwo nikan lo n wọ asọ ni tawọn yoo fi maa binu rẹ, abi ọba wo lo ri to n rin ihooho, bo ba si se wu, lo se lee lo owo rẹ.