Yoruba Foods: Ọ́pọ́ àwọn oúnjẹ wọ̀nyí ló ti ń di ìgbàgbé, táa sì gbọdọ̀ pè padà

Ẹfọ riro Image copyright Others

Ẹya Yoruba yaayi, wọn gbafẹ, wọn ni aṣa, ede ati ọpọ ohun ajogunba to jẹ manigbagbe, eyi ti ko ṣee fi ọwọ rọ sẹyin.

Ki awọn oyinbo alawọ funfun to de ni Yoruba ti n ṣe aye, wọn n wọṣọ, wọn n jẹun, ti awọn ounjẹ wọn kii si ṣe aṣadanu.

Awọn ounjẹ Yoruba gbajumọ pupọ, ti awọn ẹya miran gan ṣi kundun lati maa jẹ ounjẹ yii nitori adun rẹ ati bo ṣe n ṣe ara loore.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun apẹẹrẹ, amala, ẹba ati iyan jẹ ounjẹ abalaye iran Yoruba ṣugbọn o ti di itẹwọgba bayii lọdọ awọn ẹya miran lorilẹede Naijiria.

Ṣugbọn fun iyalẹnu ọpọ eeyan, diẹ lara awọn ounjẹ ati ọbẹ abalaye wa ti n lọ sokun igbagbe, idi si ree to fi yẹ ka pe akiyesi wa sawọn ounjẹ naa, ki wọn maa baa di igbagbe patapata.

Awọn ounjẹ ati ọbẹ manigbagbe nilẹ Yoruba:

Ẹwa Agọnyin:

Arimalelọ ni ẹwa Agọnyin, awopadasẹyin si ni pẹlu, paapa ọbẹ alata ti wọn maa n bu le e lori.

Image copyright Others

Ẹwa Agọnyin yatọ si ẹwa alasepọ to wọpọ, eyi ti wọn maa n ro epo ati ata papọ, ṣugbọn ọtọ la n din ata ori ẹwa Agọnyin.

Ẹwa pupa ni wọn maa fi n se ẹwa yii, ti wọn si maa n din ata rẹ, ti yoo gbẹ titi yoo fi din di dudu ki wọn to bu u le ẹwa naa lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Ikọkọrẹ:

Isu Ewura ni a fi n se Ikọkọrẹ, ẹlẹmi meje ni, tori ọpọ eroja ti wọn fi n se e, to si wọpọ laarin awọn ẹya Ijẹbu.

Image copyright Others

Lara awọn eroja taa nilo taa ba fẹ se Ikọkọrẹ ni Isu ewura, alubọsa, epo pupa, awọn eroja amuọbẹdun, ẹja gbigbẹ, pọnmọ, inu ẹran ati bẹẹbẹẹ lọ.

Ko si ẹni ti o foju kan Ikọkọrẹ ti ebi ko ni pa lati jẹ nitori ẹlẹmi ọgbọn ni ounjẹ ọhun.

Mọin-mọin ẹlẹmi meje:

Asọdun ni pe ounjẹ kan ni ẹmi meje amọ taa ba se mọin-mọin naa, amọ pe ko si irọ ninu orukọ ti wọn n pe.

Image copyright Others

Mọin-mọin tabi ọọlẹ ni wọn n fi ẹwa se, pẹlu eroja ata, ewe, epo abi ororo, ti wọn si maa n fi ẹja, ede, ẹyin ati ẹran wẹwẹ sinu ounjẹ yii.

Owo nla lo pa mọin-mọin ẹlẹmi meje tori ko wa fun ẹniti ko lowo lọwọ tori ọpọ eroja to nilo, to si n se ara loore pupọ pẹlu.

Egbo ati Ẹwa:

Ẹgbo ati ẹwa jẹ ounjẹ abalaye to ti n lọ sokun igbagbe bayii, to si yẹ ka pe akiyesi wa si.

Image copyright Others

Agbado gbigbẹ ti wọn ti bo, ni wọn fi n ṣe egbo, wọn yoo fẹ idọti ara rẹ kuro, ki wọn to da sori ina lati see, titi ti yoo fi rọ

Lẹyin eyi ni wọn yoo wa bu ẹwa sise le lori, eyiun ẹwa fifọ bii ẹwa Aganyin, ti wọn yoo si bu ata dindin le lori pẹlu.

Adun ẹwa Aganyin ko se fẹnu sọ nitori onibeji to jẹ, to si n fun ni lokun, agbara ati eroja asara loore.

Irẹsi Ọfada:

Bi o tilẹ jẹ pe awọn oyinbo alawọ funfun lo ko irẹsi wa silẹ yii, sibẹ, awa naa ni irẹsi tiwa n tiwa to wọpọ laarin wa ni bii adọọta ọdun sẹyin.

Image copyright Others

Irẹsi Ọfada jẹ eyi to lee wu lorilẹede yii, yatọ sawọn ẹya irẹsi miran, to si ni adun ti ko ni afiwe.

Lootọ ni irẹsi ọfada ni okuta, ams ta ba fi ara balẹ see, a gbadun rẹ ti adun rẹ ko si ni tete di ohun igbagbe.

Ọbẹ ata dindin pẹlu inu ẹran, ede, pọnmọ, inu ẹran ati iru lo mu ki ọbẹ ọfada yatọ si awọn ọbẹ ounjẹ miran, arimalelọ si ni pẹlu.

Iyan ati ẹfọ riro:

Yoruba ni iyan ni ounjẹ, ọka ni oogun, eyi to n sọ bi ounjẹ naa ti se pataki si lawujọ wa.

Image copyright Others

Alejo ti wọn ba gun iyan fun, ọba ni, nitori adun rẹ, paapa ta ba fi adiẹ se ọbẹ ata taa fi jẹ.

Isu ti wọn se lori ina, ti wọn si gun lodo lẹyin ti isu jinna tan la n pe ni iyan, ọbẹ ẹfọ riro si la saba maa n fi jẹ.

Orisirisi ẹfọ riro lo wa bii sọkọ, tẹtẹ, igbo, ati bẹbẹ bẹẹ lọ ta lee fi jẹ iyan, ti a si fi awọn eroja ẹlẹmi meje bii pọnmọ, ede, ẹja gbigbẹ, panla, igbin ati bẹẹ bẹẹ lọ se.

Akara olororo tabi Sẹẹkẹ ati akara elepo ta mọ si Kengbe:

Ẹwa ti a ti lọ kun pẹlu awọn eroja bii ọpọ alubọsa ati asa, ta wa din ninu ororo tabi epo pupa la n pe ni akara.

Image copyright Others

Akara kọja nkan ipanu nitori ounjẹ asaraloore gidi ni, to si tun maa n mu ki ara fuyẹ.

A lee fi epo tabi ororo din akara, o si wa lọwọ ta ba se fẹ si.

Akara ba ba fi ororo din la n pe ni Sẹẹkẹ, aye ode oni si lo ti wọpọ nigbati awọn oyinbo n se ororo.

Image copyright Others

Amọ laye atijọ, akara taa fi epo din, ta n pe ni kengbe lo wọpọ, ki sẹẹkẹ to de.

A le fi ede ati ẹja sinu akara ta fẹ din lati mu ko ladun, bakan naa si la lee fi ata wẹwẹ sinu rẹ ko lee ta lẹnu.

Asaro elede abi Ẹbẹ:

Eroja ounjẹ miran ti awọn ọdọ ode iwoyi ko saba kundun, to si ti n di manigbagbe lọ ni Asaro abi Ẹbẹ jẹ.

Isu taa se pẹlu ata ati epo pupa ni a n pe ni asaro, to si tun lee ni eroja amounjẹ dun bii ede, ẹjọ, inu ẹran ati bẹẹ bẹẹ lọ

Image copyright Others

Bi isu ba ti jinna tan, la fọ si wẹwẹ, ti a si fi ata ati epo si eyi to mu ki wọn maa pe ni asaro elede abi elepo rẹbẹ-rẹbẹ.

Asaro rọrun lati jẹ ju isu lasan lọ nitori ọpọ eroja asaraloore miran ta se pẹlu rẹ.

Ekuru Aro ati Ekuru funfun:

A lee pe Ekuru ni onibeji nitori Ekuru aro ati funfun maa n lọ papọ ni.

Ẹwa taa ti bo, ta si fi ẹrọ lọ lai fi ata tabi epo si la n pe ni ekuru.

Image copyright Others

Ekuru ta ba fi kaun diẹ sinu rẹ la n pe ni aro, tori kaun inu rẹ yoo jẹ ko dudu bii aro, ekuru ti a ko si fi kaun si ni wsn n pe ni ekuru funfun.

A maa n jẹ ekuru mejeeji yii papọ ni pẹlu ata dindin bii ata ẹwa aganyin, ti ata rẹ ọhun naa si maa n ni awọn eroja ẹlẹmi pupọ bii ede, ẹjọ, ẹran wẹwẹ ati inu ẹran.

Image copyright Others

Yoruba gbagbọ pe ekuru ni ounjẹ ibeji, ti wọn si maa n se fun wọn.