ALGON Oyo: Ìjọba ní àlá lásán tí kò le è dòhun ni ìlàkàkà àwọn alága APC láti padà sí káńṣù

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Oyo local government: ALGON, Makinde sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀nà àti

Awọn alaga kansu nipinlẹ Ọyọ ti sọ pe, igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ n gbe lori ọrọ aawọ laarin awọn ati ijọba, kii ṣe eyi to lee mu alaafia waye bọrọ.

Awọn alaga naa ni, ijọba Seyi Makinde setan lati san gbogbo owo oṣu ati ajẹmọnu awọn fun iye ọdun to ku, to yẹ kawọn fi pari saa awọn gẹgẹ bii alaga kansu, eyi tii se ara ilana ati pana aawọ naa, ṣugbọn awọn ko fẹ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọjọ Ẹti ni iwe kan n fẹ kiri loju awọn opo ikansiraẹni lori ayelujara pe ijọba ipinlẹ Ọ́yọ ti fi iwe ransẹ si agbẹjọro awọn alaga kansu naa, Algon, pe oun setan lati san gbogbo owo osu ati ajẹmọnu wọn, ki wọn si maa ba tiwọn lọ.

Oríṣun àwòrán, Algon Oyo

Alaga ẹgbẹ awọn alaga kansu, ALGON naa, Ọmọọba Abass Alẹṣinlọyẹ, to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe, kii ṣe owo ni awọn n fẹ bikoṣe titẹle ilana ofin nipa pipari saa awọn to ku, gẹgẹ bii alaga kansu nipinlẹ Ọyọ.

Amọ ninu ọrọ to ba ileeṣẹ BBC news Yoruba sọ, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Taiwo Adisa ni, gẹgẹ bii ijọba ti ko fẹ wahala, to si fi oju woo pe ati tọtun, ati tosi, ọmọ ipinlẹ Ọyọ ni gbogbo wọn, lo mu ki ijọba gbe aba alaafia naa kalẹ.

Oríṣun àwòrán, Ayodeji Abass Alesinloye

O ni ninu aba naa nijọba ti gba lati san awọn nnkan kan fun awọn alaga kansu naa, nitori ala ti ko lee sẹ ni igbiyanju wọn lati pada si ọọfisi bii alaga kansu, to si ni ki wọn tu itọ rẹ danu pe eyi yoo ri bẹẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, lọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ fa awọn alaga kansu latinu ẹgbẹ oselu APC, labẹ saa ijọba ana lọ sile ẹjọ pe, ki ile ẹjọ ka wọn lapa ko, ki wọn si maa pada si ipo alaga mọ.

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni, eto idibo to gbe awọn alaga kansu naa wọle tako ofin, niwọn igba ti ile ẹjọ ti ni ki wọn nisuuru ki wọn gbọ ẹjọ wọn tan, ki wọn to ṣe idibo ọhun nigba naa.

Eleyi ni wọn fa titi, ki ile ẹjọ to gba wọn laye lati lọ yanju ọrọ naa ni tubi inubi laarin ara wọn.

Ireti ọpọ ni pe, igbesẹ naa yoo tete mu ki alaafia waye lori ọrọ naa; amọṣa ọrọ ko fẹ jọ bẹẹ bayii, kaka ki ewe agbọn aawọ ọhun si dẹ, ko ko ko lo n le si.

Oríṣun àwòrán, Ayodeji Abass Alesinloye

Ko si idi meji fun eyi, ju iroyin kan to n lọ kaakiri pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti na ọwọ alaafia si ẹgbẹ awọn alaga kansu naa, ALGON.

Ni ọjọ Ẹti lawọn alaga kansu ọhun kọkọ gba ile ẹjọ lọ, lati fi to ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ leti pe awọn ti tẹwọgba eto ti ijọba fi silẹ fun yiyanju aawọ naa, ṣugbọn awọn ko tii yiri rẹ wo.

Àkọlé fídíò,

Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀le nínú àgbékalẹ̀ Amotekun - Alake ti Egba