SARS: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Remo Stars ní ikọ̀ SARS ló pa agbábọ́ọ́lú òun

Tiyamiyu Kazeem

Oríṣun àwòrán, @RemoStarsSC

Ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars ti fẹsun ipaniyan kan ikọ ọlọpa to n gbogun ti iwa idigunjale, Special Anti-Robbery Squad, SARS, nipinlẹ Ogun. pe ikọ naa lo pa Tiyamiyu Kazeem, to jẹ ọkan lara ọmọ ikọ ọhun.

Alukoro ẹgbẹ agbabọọlu naa, Dimeji Oshode sọ ninu atẹjade kan pe, iṣẹlẹ naa waye lopopona Sagamu nigba ti ologbe ọhun ati akẹgbẹ rẹ, Sanni Abubakar n rinrin ajo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn ikọ SARS da Kazeem duro, ti wọn si fi ẹsun kan pe o jẹ ọmọ Yahoo, oni jibiti ori ayelujara, nitori imura rẹ, ṣugbọn o ṣalaye fun wọn pe iṣẹ bọọlu gbigba ni oun n ṣe.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe, Kazeem fi kaadi idanimọ rẹ han awọn agbofinro naa gẹgẹ bi agbabọọlu, ṣugbọn wọn kọti ikun sii.

Lẹyin-o-rẹyin, wọn fi panpẹ ofin mu, o si gba lati tẹle wọn lọ si agọ wọn.

Ṣugbọn lẹyin ti wọn n gbe lọ loju ọna marosẹ Sagamu si Abeokuta, lo ba beere ibi ti wọn n gbe oun lọ, nitori ibi ti wọn dorikọ yatọ si ọna agọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Tiyamiyu Kazeem

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, lẹyin eyii ni awọn ọlọpaa naa duro, ti wọn si tii jade ninu ọkọ wọn, eyi to mu ki ọkọ mii to n bọ kọlu, to si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe.

Ẹwẹ, ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe, ikọ SARS ipinlẹ naa ko mọwọ mẹsẹ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, @RemoStarsSC

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ fun awọn akọroyin pe, ikọ SARS kọ lo pa Kazeem, o ni lootọ ni ikọ naa kan fi pampẹ ofin mu pe o wọ aṣọ ṣọja.

O ni lẹyin ti wọn n gbe lọ ni ọkọ wọn taku loju ọna, ṣugbọn nigba ti ologbe naa gbiyanju ati sọda loju popo, ni ọkọ miran kọlu.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni n fi ero wọn lede, lẹyin iroyin iku agbabọọlu naa, ti wọn si n bu atẹ lu ikọ SARs naa.