Boko Haram: Ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ náà kó òògùn òyìnbó, oúnjẹ́ tí wọ́n sì tún pa ọmọogun mẹ́ta

Awọn ologun ati araalu niluGarkida

Oríṣun àwòrán, @jorowasinda

Ilu Garkida to wa nijọba ibilẹ Gombi nipinlẹ Adamawa gbona jain-jain lalẹ ọjọ Ẹti nigba ti ikọ aṣẹrubalu Boko Haram kọlu ilu naa, to si ti si ti fọwọ gbaya pe oun gan loun wa nidi ikọlu ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni, bi eeyan ba jẹ ori ahun, yoo papa bu sẹkun to ba ri ọwọja ikọlu ọhun bo se lagbara si, nitori awọn agọ ọlọpa ati baraki wọn, ọpọ ile ijọsin, ilegbe, to fi mọ ile ajagunfẹyinti Paul Tarfa, ni wọn jo kanlẹ.

Gbọnmọ-gbọnmọ awọn ikọlu awọn ikọ afẹjẹwẹ wọnyi lo ti wa n legba kan ju ọrin lọ nilẹ Naijiria lẹnu lọọlọ yii, kaka ki ewe agbọn wọn si dẹ, koko lo n le si.

Oríṣun àwòrán, @jorowasinda

A gbọ pe wakati mẹfa gbako ni wọn fi da ilu Garkida naa, to wa loju ọna Damaturu laamu, eyi ti ko jinna si guusu Borno ati igbo Sambisa.

Ikọ asẹrubalu Boko Haram naa ni ọmọ ogun mẹta ni oun gbẹmi wọn, toun si ti mu awọn olujọsin tọwọ oun ba lawọn ile ijọsin ni igbekun, to fi mọ awọn olugbe abule naa.

Oríṣun àwòrán, @jorowasinda

Ileesẹ ọmọogun Naijiria ni awọn se bi akin, tawọn si wọya ija pẹlu awọn ikọ afẹjẹsofo naa, ti ibọn n dun lakọlakọ, amọ awọn olugbe ilu naa ni awọn ti tete kofiri awọn awọn ọmọ ikọ asẹrubalu naa lati okeere, tawọn si ta awọn ọmọ ogun lolobo.

Oríṣun àwòrán, @jorowasinda

Amọ dipo ki wọn se isẹlẹ naa ni ogun ti yoo ka ni mọle, okeere laa tii ko, se ni wọn, eyi ko ri bẹẹ, tawọn ikọ naa fi wọle ti awọn lọpọ yanturu, ti wọn si bẹrẹ si ni ja ilu naa lole loju ibọn.

Àkọlé fídíò,

Cerebral Palsy: Ìyá Najeebah ní oyún oṣù mẹ́rin ààbọ ni wọn gbe jáde kúrò nínú òun

"Bi wọn se n ko oogun oyinbo ninu ọpọ sọọbu, ni wọn n fọ ilegbe ati ibudo itaja fun eroja ounjẹ lai si ẹni ti yoo yẹ wọn lọwọ wo. Wọn pa ọpọ eeyan, ti wọn si tun ba ọkẹ aimọye dukia jẹ, to fi mọ ile ajagunfẹyinti Paul Tarfa."