Mathematics Education: Fasiti Ibadan f'orin tàkasúfèé wá ojúùtú si ìṣòro ẹ̀kọ́ ìṣirò

Fasiti UI

Oríṣun àwòrán, UI

Àkọlé àwòrán,

Fasiti UI forin tàkasúfèé wá ojúùtú si ìṣòro ẹ̀kọ́ iṣirò

Lójúnà ati wá ojúútú si bi àwọn ènìyàn ṣe maa n fìdírẹmi nínú ẹkọ ìsirò yála nilé ìwé alákọbẹ́rẹ̀ tàbi ni girama lásìkò ìdánwò, olùkọ́ni kan láti ẹka ẹkọ àwọn ọmọde ni Fasiti Ibadan, Omowe Ishola Salami ti ṣe àgbekalẹ̀ orin tàkasúfèé láti mu ẹkọ náà rọrùn.

Salami to ni pàtàkì ǹkan to jẹ òun lógun ni ìmọ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, sàláyé pe orin tàkasúfèé náà ni ọ̀nà láti mu ki ọpọlọ àwọn ọmọ ilé-ìwé alákọbẹ́rẹ́ ẹkọ ìmọ isirò ṣí kíákíá.

Salami ni "ẹníkẹni to ba lé wá ojúutu si ẹkọ ìṣìrò lé wá ojúutu si ìsòrò tó bá ń ṣẹlẹ̀ láwujọ rẹ̀."

Lasìkò to n sàlàyé lóri ìmọ tuntun tó gbékalẹ̀, ó ṣàlàyé pé orin tàkasúfèé tí òun pè ní MATMusic, ni àwọn orin tó ni àwọn ìmọ̀ ìṣìrò ti jẹ ki ó rorùn nínú.

Idanwò WAEC ni ọdun 2019 fi han pé nínú àwọn ọmọ to dín díẹ̀ ńi ẹgbẹ̀run mejilà to kọ ìdánwo náà, agbara káká ni a fi ri eniyan ẹgbẹ̀run mẹta to gba àmì Krediiti marun to si ni Isiro àti èdè Gẹẹsi nínú.

Kíkọ ìmọ̀ ìṣìrò ti jẹ̀ ìṣòrò fun ọ̀pọ̀ láti ìgbà to ti pẹ́ láti ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ jákèjádò gbogbo àgbàyé, ǹkan to si fa irú iṣòro yii ni pé ìmọ ẹkọ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ofin ti a ko le foju ri ṣùgbọ́n ti a gbọ̀dọ fi pamọ sinu ọpọlọ ní.

Bákan náà ni ìwádìí fi hàn pé ti awọn ọmọde ba fẹ́ràn orin ti wọ́n gbọ́, wọ́n maa n ranti àwọ́n ọ̀rọ̀ inú orin náà, nítori náà ti gbogbo àwọn ìlàna àti òfin inu ìsìrò ba di orin, èyi yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́.

"Tori ìdí èyi gàn ni mo ṣe ṣe àkojọ àwọn orin to ni ṣe pẹlu imọ ìṣiro fun àwọn ọmọ ilé-iwé alakọbẹ̀rẹ̀."

"Mo si ní ìgbagbọ́ pé àwọn ìjọba gúúsù-ìwọ̀-òòrun Naijiria yoo gba ìmọ̀ tuntun yìi wọ́le ti wọ́n yoo si ma lò ó láwọ́n ilé ẹkọ lakọbẹ̀rẹ̀"