Nigeria border closure: Ìdí tí Ààrẹ Buhari kò ṣe tíì ṣí ibodè tó tì pa rèé

Buhari

Oríṣun àwòrán, @alabiopeyemiola

Àkọlé àwòrán,

Buhari parọwa si awọn orilẹ-ede ti ọrọ naa kan lati ni suuru

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun n duro de esi igbimọ to n ri si ọrọ ibode to di titi pa, eyi ni "Tripartite Committee" ko to gbe igbeṣẹ to kan lori ibode ọhun.

Buhari lo sọ orọ yii nibi ipade kan to ṣe pẹlu aarẹ orilẹ-ede Burkina Faso, Roch Marc Christian Kabore, to si ṣeleri pe atunṣe yoo waye lori ọrọ ibode naa to di titi pa laipẹ.

O ni oun ṣe tan lati ṣe ohun to yẹ lai fi akoko ṣofo ni kete ti igbimọ naa ba ti fi esi wọn ranṣe.

Awọn to wa ninu igbiimọ naa ni; ijọba Naijiria, ijọba Benin ati ijọba Niger Republic.

Buhari sọ pe "ootọ ni pe orilẹ-ede Naijira mọ erongba awọn orilẹede to yi wa ka ati ajọ ECOWAS lori ibode ti a gbe agadagodo si, ṣugbọn a o wa ojutu si ọrọ naa laipẹ."

Oríṣun àwòrán, @Buharisallau1

Àkọlé àwòrán,

Awọn to wa ninu igbiimọ naa ni; ijọba Naijiria, ijọba Benin ati ijọba Niger Republic.

O ṣalaye pe idi kan gboogi ti awọn ibode ọhun ṣe di titi pa ni eto aabo to mẹhẹ, paapaa julọ nitori bi awọn kan ṣe n ko ohun ija ogun ati egboogi oloro wọ orilẹede yii.

Lẹyin naa ni aarẹ Buhari wa parọwa si awọn orilẹede ti ọrọ naa kan lati ni suuru.

Ẹwẹ, alaga igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnatọ Walid Jibrin ti sọ pe ibukun nla ni igbesẹ ijọba Buhari lati gbe agadagodo sẹnu ibode Naijiria.

Jibri sọ ọrọ naa gẹgẹ bi alatilẹyin ẹgbẹ awọn oniṣowo aṣọ ni Naijiiria, lẹyin to ti ṣe iṣẹ gẹgẹ bi oniṣowo aṣọ fun ọdun marundinlaadọta.

Àkọlé fídíò,

Àwọn olúlùfẹ́ fí ìbòjú fi ẹnu ko ara wọn ní Philippine

O ṣalaye pe bi ijọba ṣe ti awọn ibode naa ti ṣe adikun si bi awọn kọlọransi kan ṣe n ko aṣọ wọle si Naijiria lọna ti ko ba ofin mu.

Jibri sọ pe igbesẹ lati ti ibode naa jẹ ọkan gboogi lara aṣeyọri aarẹ Buhari lati ri pe awọn ileeṣẹ to n ṣe aṣọ lorilẹ-ede yii gbera sọ.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá