Tiamiyu Kazeem: Ọlọ́páà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fìyà jẹ ará ìlú tó bá wọ aṣọ ológun - Amofin

Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @others

Amofin kan, Banjo Ayenakin ti sọ pe ọlọpaa ko lẹtọ labẹ ofin lati fiya jẹ ẹnikẹni ti wọn ba gbamu pe o wọ aṣọ ologun ti kii si n ṣẹ ọmọ ologun.

Ayenakin lo sọ ọrọ naa fun BBC Yoruba lẹyin iku Tiamiyu Kazeem to ṣagbako iku lati ọwọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS, ti wọn ni wọn fofin mu latari pe o wọ aṣọ ologun lai jẹ ọmọ ogun.

O ni "Ti ọlọpaa ba mu ẹnikẹni pẹlu aṣọ ologun, wọn ko laṣẹ lati fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ tabi ki wọn lu."

Amofin ọhun tẹsiwaju pe o yẹ ki wọn fi pampẹ ofin mu ọlọpaa to ba lu eeyan nitori pe o wọ aṣọ ologun.

Ṣugbọn amofin naa ṣalaye pe , gẹgẹ bi ofin ṣe gbe kalẹ, ẹni ti kii ba n ṣe ọmọ ologun ko ni aṣẹ lati wọ asọ ologun lorilẹ-ede Naijiria.

O ni "O lodi si ofin ati pe ijiya n bẹ fun ẹnikẹni ti ọwọ ofin ba tẹ pe o wọ aṣọ ologun ti ko si jẹ ọkan lara ọmọ ogun Naijiria.

Ayenakin ṣalaye fun BBC Yoruba, ẹsẹ ofin to ni ṣe pẹlu iwa ọdaran, iyẹn "Criminal code" to sọ ijiya to wa fun ẹni to ba wọ aṣọ ologun.

O ni ijiya to wa fun ẹni to ba wọ aṣọ ọmọ ogun laarin igboro ni pe yoo san owo itanran ẹgbẹrun meji tabi ko ṣewọn oṣu kan.

Ṣugbọn ẹni to ba wọ aṣọ ọmọ ogun lati fi tan ara ilu jẹ pe ologunn ni oun ti ko si ri bẹẹ, yoo lọ si ẹwọn oṣu mẹfa.

Àkọlé fídíò,

Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Ẹwẹ, amofin naa sọ siwaju sii pe ẹni to ba wọ aṣọ ologun lati fi ṣe ere ori itage, tabi ẹni ti gomina tabi aarẹ ba fun ni aṣẹ lati wọ aṣọ naa ko lẹtọ si ijiya kankan labẹ ofin.

Ayenakin pari ọrọ rẹ pe ofin ko faye gba ọlọpaa kankan lati fiya jẹ ara ilu nitori pe o wuwa ọdaran.

O ni ofin faye gba ara ilu lati foju ba ile ẹjọ, ko si sọ tẹnu rẹ lori ohun ti wọn ba ka mọ lọwọ kaka ki ọlọpaa fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Tiamiyu Kazeem: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ní dandan, àwọn yóò ṣewadii ikú Tiamiyu Kazeem

Oríṣun àwòrán, @Official3SC

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Tiamiyu Kazeem, to jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars ti ipinlẹ Ogun ko ni lọ lai foju wina ofin.

Kazeem di oloogbe lopin ọsẹ to kọja yii, lẹyin ti wọn ni awọn ọtẹlẹmuyẹ Special Anti-Robbery Squad, SARS lo fa ṣababi iku rẹ lopopona Sagamu si Abeokuta.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ko lọwọ ninu iku arakunrin ọhun, ṣugbọn wọn ni wọn fi pampẹ ofin mu u nitori o wọ aṣọ ologun, ti kii sii ṣẹ ọmọ ogun Naijiria.

Ṣugbọn ẹni ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ pe, awọn SARS mu Kazeem lẹyin ti wọn fẹsun jibiti ori ayelujara kan an, to si sọ fun wọn pe iṣẹ bọọlu gbigba ni oun n ṣe, ṣugbọn awọn ọlọpaa kọti ikun si aroye rẹ.

Wọn ni igba ti wọn n gbe e lọ ninu ọkọ wọn ni wọn ti ti i lati inu ọkọ naa, to si ko sẹnu ọkọ mii to n bọ, leyi to mu ko jẹ Ọlọrun nipe.

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

Gomina Abiodun ti wa parọwa si awọn awọn ọmọ ikọ Remo Stars atawọn ọmọ ipinlẹ Ogun lati ma tẹ oju ofin mọlẹ nitori wọn n fẹ idajọ ododo fun arakunrin wọn to d'ologbe.

Ninu atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Kunle Somorin, Abidoun sọ pe ẹnikẹni lara awọn agbofinro ti aje ọrọ ọhun ba ṣi mọ lori yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Gomina ọhun sọ pe ijọba yoo ṣe iwaadi finifini lori ọrọ naa lati mọ pato ọhun to ṣẹlẹ gan latari bi ọrọ ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ati ọrọ awọn ọlọpaa ṣe yatọ.

Abiodun wa kẹdun iku ologbe naa, to si sọ pe ijọba rẹ ko ni fọwọ yẹpẹrẹ mu eto abo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò,

Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá