Africa Eye: Ìyá mi, bí mo bá rántí ikú rẹ lásìkò ìrọbí, àìbímọ tèmí ń pa mí kú díẹ̀díẹ̀

Ìyá mi, lórí pé o fẹ́ pe ọmọ wáyé, o sọ ẹ̀mí tìrẹ nù, torí emi gan ò lè bímọ, mo tí ń kú díẹ̀ díẹ̀ báyìí.

Ninu fidio yii to jẹ akanṣe fọnran ẹka ileeṣẹ BBC to maa n tu aṣiri aidaa lawujọ, BBC Africa Eye, arabinrin kan to jẹ akọroyin ati aṣefiimu lọ sinu yara ibimọ nile iwosan kan lati lọ ya fiimu bi obinrin naa ṣe n bimọ lọwọ lọwọ.

O fi eyi ran ara rẹ leti ohun ti iya rẹ la kọja.

O ni ṣe ni ohun n ranti bi iya ti oun ṣe ku lasiko to n rọbi lati bimọ.

Bo tilẹ jẹ pe iya rẹ bi ọmọ naa saye, o gba ibẹ lọ.

Aicha wa lọmọ ọdun marun nigba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ti eeyan lee ni ọmọde o mọ nkankan ṣugbọn lati igba ti oun gan ti wọ ile ọkọ bayii, ti ko gbọ pa tabi gbọ po, ni omije ti bẹrẹ si ni bọ ni oju rẹ́ ti irẹwẹsi si n wọ ọ lọkan.