Komla Dumor Award 2020: BBC ń wá ìràwọ̀ akọ̀ròyìn tí yóò sọ ìtàn Áfíríkà

Komla Dumor
Àkọlé àwòrán,

Ami ẹyẹ Komla Dumor jẹ fún iranti akọni to lọ

Lonii ọjọ aje, ileeṣẹ BBc n ṣe ifilọlẹ ọdun kẹfa ami ẹyẹ pataki kan fun iṣ iroyin ni iranti oloogbe akọroyin ọmọ orilẹede Ghana kan, Komla Dumor to ṣaadede ku ldun 2014 lni dun mọkanlelogoji.

Erongba ami yẹ naa ni lati ṣawari ati lati ṣe agbende awọn irawọ Afirika to ṣẹṣẹ n dide ninu iṣẹ iroyin ti yoo si tubọ ṣe afihan ẹbun rẹ bii ti oloogbe Komla Dumor to n sọ itan Afirika lọna to jinlẹ to si tun n gbe ogo ati idayatọ ilẹ adulawọ jade pẹlu gbogbo agbara rẹ ati ifarajin.

Àkọlé fídíò,

BBC ṣe'filọlẹ ami ẹyẹ Komlar Dumor

Awọn to ti jawe olubori gba ami ẹyẹ Komlar Dumor ti ileeṣẹ BBC ri ni Nancy Kacungira ati Solomon Serwanjja ti orilede Uganda, didi Akinyelure ati Amna Yuguda ti orilẹede Naijiria to fi mọ Waihiga Mwaura ti Kenya.

Ilu Johannesburg lorilẹede South Africa ni ifilọlẹ ti ọdun yii yoo ti waye pẹlu eto ipade itagbangba BBC kan ti wọn yoo ṣafihan ati agbejade rẹ lori eto ori rẹdio Focus on Africa ati BBC World Service .

Ẹni to ba gbegba oroke ninu idije yii yoo lo oṣu mẹfa ni ile igbohunsafẹfẹ ti BBC to wa niluu London ti yoo si ba awọn oniroyin to moye ju lagbaye ṣiṣẹ pọ lati kọ ẹkọ ati imọ kun imọ.

Oju opo ti wa ṣi silẹ bayii fun awọn to ba fẹ kopa ninu idije lati gba ami ẹyẹ Komla Dumor ti BBc fun ọdun yii, 2020 titi di oru ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta ọdun 2020 nipasẹ lilọ si oju opo itakun agbaye www.bbc.com/komladumor.