Heatwave: Ìyàtọ̀ ojú ọjọ́ ló fa ooru gbígbóná lásìkò yìí

Heatwave

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ń ké ìrọra ooru gbígbóná lasiko yii pẹ̀lú àwòrán lórí ayélujára láti ṣe àfihàn bí oru náà ṣe n báwọn fínra.

Onimọ nipa eto isegun kan ti parọwa si awọn eniyan lati ma wọ aṣo ti yoo gba atẹgun laye lasiko ooru gbigbona yii.

Dokita Ikubese Wilson lo ṣe agbekalẹ awọn ọna ti eeyan le fi koju oru gbigbona to n ja rain kaakiri orilẹede Naijiria.

Dokita naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ayipada oju ọjọ, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni climate change lo ṣokunfa bi ayika ti ṣe gbona jainjain yi.

Awọn eniyan tilẹ n fi aworan si ori ẹrọ ayelujara lati le ṣe afiwe bi o ṣe ri ni ara wọn lasiko ooru gbigbona yii, paapaa ni alẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹ wo ohun ti ẹ le ṣe lati koju ooru gbigbona lasiko yii:

  • Ẹ mu omi daadaa ni gbogbo igba ki omi gbigbona ara le kuro
  • Ẹ wo aṣọ ti yoo jẹ ki atẹgun fẹ si yin lara.
  • Ẹ wẹ ju ẹẹkan lọ ki ẹ to sun
  • Ẹ pẹ ni baluwẹ, ki omi le pẹ ni ara yin daadaa.
  • Ẹ ma fi aṣọ tabi tawẹli nu omi ara yin kuro lẹyin ti ẹ ba wẹ tan.
  • Faanu tabi ẹrọ amule tutu ṣe koko lasiko yii nitori ina ọba to n ṣe segesege.
  • Ẹ si ferese sile ni alẹ nitori ki ooru to ti wọ ile le jade sita lai pa awọn eniyan.
  • Ẹ gba abẹrẹ ajẹsara fun awọn ọmọde ni asiko.

Bakan naa ni dokita naa sọ pe awọn aisan to wọpọ ni asiko yii ni aisan to n ba ẹyin oju ja, aisan yirun yirun, ti awọn oyinbo n pe ni meningitis, CMS ati aisan igbona(measles), aisan onigba meji, ikọ ati awọn aisan to ma n ṣe awọn eniyan ni ọnafun.