#SagamuOnFire: Àwọn ẹbí Tiamiyu bèrè fún ìwádìí tòótó lórí ikú ọmọ wọn

Ogun

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ṣe àbẹwò ìbánikẹ́dùn sí àwọn òbí Tiamiyu Kazeem tí àwọn ọlọ́pàá pa.

Awọn obi agbabọọlu ikọ Remọ Stars, Tiamiyu ti bere fun iwadii otitọ lori iku to pa ọmọ wọn nipasẹ awọn ọlọpaa.

Mama Tiamiyu sọ ọrọ yii lasiko ti gomina Dapo Abiọdun ṣe abẹwo si awọn obi Tiamiyu ni ile wọn.

Iya ọmọ naa ni ọmọ awọn, ọdun mẹtadinlọgbọn kii si ṣe yahoo yahoo.

O bere fun idajọ ododo ati iya to tọ fun awọn to pa ọmọ rẹ, nitori olu ọmọ ni ọmọ naa, ati wi pe iya naa ko gbọdọ jẹ oun gbe.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun nigba to n fesi nibi to ti lọ ba awọn obi naa kẹdun, ṣeleri pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Abiodun ni awọn ọlọpaa to pa ọmọ naa kii ṣe ọlọpaa ipinlẹ Ogun lati ọdọ adari zone ni wọn ti wa.

O fikun un wi pe Kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ọba mu gbogbo awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan.

Gomina Dapo Abiodun fikun un wi pe Igbakeji Aarẹ Orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo naa ti fi ẹdun rẹ ranṣẹ si awọn eniyan ipinlẹ ọhun.

Nitori naa ni gomina ṣe rọ awọn ẹbi ati ara Tiamiyu lati mu ọkan le, ati wi pe awọn yoo ṣe iranlọwọ fun wọn ni gbogbo ọna ti awọn lee gba.

Ninu ọrọ tirẹ, Igbakeji ọga agba ọlọpaa to wa ni ẹka iwadii iwa ọdaran, Peter Ogunyonwo to ṣoju ọga agba ọlọpaa, Mohammed Adamu naa ba ẹbi ati ara kẹdun.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ogunyonwo ni ọga agba ọlọpaa ti gba iṣẹ lọwọ awọn ikọ Zonal Intervention Squad, Obada-Oko ni ipinlẹ Ogun to wa ni idi iṣẹlẹ iṣekupani naa.

Tiamiyu Kazeem ni ọkọ oju popo pa lẹyin ti awọn ọlọpaa SARS ti i jabọ kuro ninu ọkọ wọn ni ọna Abeokuta-Sagamu ni ọjọ Satide.

Kazeem ki o to ku ni igbakeji balogun ikọ agbabọọlu Remo Stars.

Ó kéré tán, ẹ̀mí méjì míì ti lọ lórí ìfẹ̀hónú han Sagamu láàrin Ọlọ́pàá àti aráàlú

Ọga ọlọpaa patapata lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ fun ọga ọlọpaa to wa lẹka iṣewaadi iwa ọdaran, Anthony Ogbizi lati ṣewadi ohun to fa iku Tiamiyu Kazeem to d'oloogbe nipinlẹ Ogun.

Adamu lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Oríṣun àwòrán, @policeng

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti rogbodiyan to bẹ silẹ nilu Sagamu lẹyin iku arakunrin naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars.

Ọga ọlọpaa patapata ti ba awọn ẹbi ologbe naa kẹdun, to si fi da wọn loju pe wọn yoo ri idajọ ododo gba lori iṣẹlẹ naa.

Tiamiyu Kazeem gbẹmi mi lọjọ kejilelogun, Oṣu keji ọdun 2020 lẹyin ti wọn sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ SARS ti lati inu ọkọ, ti ọkọ mii to n bọ si kọluu, leyi to mu ko njẹ Ọlọrun nipe.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa kọkọ ṣe pe oun ko lọwọ ninu iku okunrin naa, ṣugbọn awuyewuye to tẹlẹ iṣẹlẹ ọhun ko kere rara.

Oríṣun àwòrán, @RemoStarsSC

Ọpọ awọn Naijriia lo ti bẹrẹ si n fi eroungba wọn lede loju opo Twitter lori iṣẹlẹ naa pẹlu ami #End SARS, pe ki ijọba gbẹsẹle ẹka ileeṣẹ ọlọpa to n risi ọrọ awọn adigunjale, iyẹn SARS.

Yatọ si Tiamiyu Kazeem to dologbe yii, ọpọ igba lawọn eeyan ti fẹsun kan awọn oṣiṣẹ SARS yii pe wọn n tẹ oju ẹtọ awọn ọmọ Naijiria mọlẹ.

Àkọlé fídíò,

Ìlú Eko ló jẹ gbèsè jù ní Nàìjíríà lẹ́yìn ìjọba àpapọ̀