Dele: 'Oṣù mẹ́jọ ni wọ́n tí yọ ina wa ló jẹ́ kí Dele lọ ṣe iṣẹ́ àmúrelé nídìí ẹ̀rọ ATM

Àkọlé fídíò,

Dele, ọmọdé tó ń fi iná ẹ̀rọ ATM ṣe iṣẹ́ àmurelé sọ ìdí tó fi kára mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ fún BBC Yorùbá

Rasheed Fathia Dele ni iṣẹ nọọsi ni oun fẹ ṣe lọjọ waju lo jẹ ki oun mura si ẹkọ oun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ diẹ sẹyin ni okiki ọmọdebinrin yii kan kaakiri agbaye lori ayelujara pẹlu aworan rẹ ti eeyan kan fi sori ayelujara.

Aworan naa ṣafihan Dele to n fi itanna ẹrọ ipọwo ATM ṣe iṣẹ amurele rẹ lalẹ ọjọ kan.

Bada Maruf Mathew, ẹni to fi aworan Dele sori Twitter to si gbilẹ kaakiri ni nini imọlara ohun ti ọmọde yii n la kọja gẹgẹ bi baba ẹlomiran lo wu oun lori.

O ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ gan to ṣe kongẹ mọde yii ni ipo to wa to bẹrẹ sidi ẹrọ ATM to si n kọ iwe.

O ni nigba ti ọmọde yii ri oun, "o sun sẹyin, o jẹ ki n gba owo tan, o tun wa pada wa, ...

Samuel Veronica to jẹ iya iya Dele kẹnu bọ ọrọ pe ai ri owo ina san ti iya onile awọn si yọ ina awọn

"O ti tó oṣù mẹ́jọ tí wọ́n ti yọ ina wa ló jẹ́ kí ọmọ yẹn lọ ṣe iṣẹ́ àmúrelé nídìí ẹ̀rọ ATM.

Ọgbẹni Bada wa bu ẹnu atẹ lu iroyin kan to n ja rainrain pe ile ifowopamọ kan ti fun ọmọdebinrin ọjọ naa lẹ́bun owo

Ọga ileewe Dele gba awọ́n ọmọ ile to ku ni imọran ki wọn gbiyanju lati maa ṣe gẹgẹ bi Dele ṣe ṣe to lo anfani to ni

Àkọlé fídíò,

Ìlú Eko ló jẹ gbèsè jù ní Nàìjíríà lẹ́yìn ìjọba àpapọ̀