Hosni Mubarak: Ààrẹ́ Egypt tẹ́lẹ̀ jáde láyé

Aarẹ Hosni Mubarak

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Egypt tẹlẹ, Hosni Mubarak ti awọn ologun le kuro niluu lọdun 2011 ti dagbere faye ni Cairo lẹni ọdun mọkanlelaadọrun.

Mubarak lo ọgbọn ọdun nipo gẹgẹ bi aarẹ Egypt ki wahala nla kan to suyọ nilẹ Egypt.

Wọn ri i pe o jẹbi ẹsun ipaniyan awọn afẹhonu han lasiko iwọde kan. Ọrọ pada yi pada ti wọn si da a silẹ ninu oṣu kẹta ọdun 2017.

Ile iṣẹ iroyin ilẹ Egypt lo kede ipapoda rẹ lọjọ aje. Ṣaaju eyi, o ti kọkọ jade loju opo itakun agbaye Al-Watan pe o ku ni ile iwosan awọn ologun ni Cairo.

Mubarak ṣe iṣẹ abẹ ni ipari oṣu kinni ọdun yii ti ọmọ rẹ, Alaa si sọ ni ọjọ abamẹta pe o wa ni ibudo awn to nilo itọju pataki.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ologun ni Hosni Mubarak; ṣugbọn iru ologun tirẹ, ẹni to gbe opo ifarajin orilede rẹ si alafia agbaye.

Labẹ iṣejọba rẹ, orilede Egypt ko ipa adari lati ri i pe ibadowo pọ wa laarin orilede Israel ati Palestine.

Ọgbọn ọdun to lo lori alefa wa sopin lọdun 2011 nigba ti wahala nla kan ṣẹlẹ to si ko o ni papa mra kuro lori itẹ.

O doju kọ iṣoro gan pe o lo aṣẹ konile o gbele lati doju kọ awọn alatako oloṣelu; si eyi igbẹyin aye rẹ, gbigbogun ti iwa ibajẹ lo fi ṣe.

Mubarak gẹgẹ bi ọmọ ogun oju ofurufu

Muhammed Hosni sọ wi pe ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 1928 ni wọn bi Mubarak ni Kafr-El Meselha ni iha ariwa Egypt.

Bi o tilẹ jẹ pe atapata dide ni, o kawe gboye ni ileewe awọn ọmọ ogun il Egypt ldun 1949 ko to rekọja lọ si ileeṣẹ awọn ọmọ ogun ofurufu nibi ti wọn ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ lọdun 1950.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun meji lo lo to n wa ọkọ ofurufu awn ologun. Asiko ti wọn pa ọgagun Gamal Abdel Nasser lọdun 1952.

Mubarak fẹ Suzanne, ọmọ ọdun mtadinlogun to tun jẹ ọmọ dokita. Mubarak goke lẹnu iṣẹ rẹ titi to fi di ọga ileewe awọn ọmọ ogun oju ofurufu ati ọga patapata awọn ọmọ ogun oju ofurufu lọdun 1972.

Akogun nla nilu

Ẹwẹ, lori ipo rẹ to kan lo ti ni orukọ to di gbajugbaja gẹgẹ bi olori ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ Egypt ati minisita fun eto abo.

Mubarak wulo gan ninu pipilẹ ikọlu ojiji ti wọn ṣe si ikọ ogun Israel ninu ogun Arab ati Isreal ni ibẹrẹ ọdun 1973.

Orilẹede Russia ati ilẹ Amẹrica wa wọya ija gidi gan gẹgẹ bi wọn ṣe n yara ko awọn ikọ ogun wọn sita. Orilẹede Israel yẹ ikọlu ṣugbọn ti ilẹ Sinai pada ko sọwọ Egypt.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbakeji Aarẹ

Ere Mubarak wa lẹyin ọdun meji, nigba aarẹ Anwar Sadat fi i ṣe igbakeji rẹ.

Mubarak gbajumọ ọrọ abẹle ṣugbn nigba naa o bẹrẹ si ni so okun irẹpọ yi pẹlu awọn adari ilẹ Arab paapaa ju lọ ọmọ ọba Saudi, Fahd.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ija nla kan ṣẹlẹ lọdun 1981 ti awọn sọja to n gbaruku ti ọkan larra awọn ẹgbẹ apani kan ṣekupa aarẹ Sadat lasiko yiyan bi ologun ti wọn fi ṣe ayẹyẹ iṣẹgun rẹ nigba ogun Arab ati Isreal lọdun 1973.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alafia de

Mubarak jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ pẹlu ida mejidinlọgọrun gbogbo ibo to jẹ pe oun nikan ni oludije.

Ipa pataki to ko ninu ilana alafia ilẹ Palestine ati Isreal fẹsẹ ibaṣepọ rẹ mulẹ pẹlu awn aarẹ to jẹ lorilẹede America ti wọn si n fun un ọpọlọpọ biliọnu dollar owo iranwọ.

Awọn mii tilẹ n bu u pe gọngọsu to n tẹle America ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin igba diẹ, wọn pe Mubarak to ti n ṣe daadaa lẹ́jọ́[. Lori akete aisan, o doju kọ ẹsun to ni ṣe pẹlu iwa ibajẹ ati ipaniyan.

Ikọ alatilẹyin rẹ n fọwọ sọya pe oun ṣi ni aarẹ Egypt tori naa ko si labẹ ile ẹjọ.

Lẹyin oṣu mẹfa, wọn yi ipẹjọda. Wọn si fi si atimle ileegbe ni ileewosan awọn ologun ni Cairo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu oniruuru idajọ, wọn wẹ mubarak mọ ninu awn ẹsun iwa ibajẹ ṣugbn fi ti ikowojẹ kan an.

Lọdun 2017, Ile ẹjọ giga ilẹ Egypt fi ẹsun kan an pe o pa awọn afẹhonu han wọn si tu u silẹ.

Hosni Mubarak si jẹjẹ lati maa sin il Egypt titi di igba ti ẹlẹmi gba ẹmi lọwọ rẹ.