Ààrẹ Buhari ṣí ilé iṣẹ́ àti afára ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ondo

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buihari ati Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti ṣe ifilọlẹ akanṣe iṣẹ ni ipinlẹ Ondo.

Gomina Akeredolu to gbalẹjọ aarẹ Buhari ni ipinlẹ naa ṣi ile itaja nla ni ilu ọrẹ ati afara to la ilu naa kọ ja ni ọjọ kẹẹdọgbọn, Osu Keji, ọdun 2020.

Akeredolu ni igbalejo aarẹ naa pẹlu ayẹyẹ ọdun kẹta ti oun bẹrẹ iṣejọba ni ipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gomina ipinlẹ Ondo to paṣẹ ọjọ isinmi lo ni fun awọn ara ilu lati gbalejo aarẹ Muhammadu Buhari, rọ awọn araalu lati lo ile itaja naa fun idagbasoke ipinlẹ Ondo ati Naijiria lapapọ.

Bakan naa ni Gomina Akeredolu ta aarẹ Buhari lọrẹ pẹlu aṣọ ibilẹ ti wọn ṣẹ ni ipinlẹ naa fun igbelaruge ọrọ aje labẹle lorilẹede Naijiria.

Awọn lọbalọba ni ipinlẹ naa ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iṣẹ akanṣe naa.

Gomina ìpinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu fi àṣọ ìbílẹ̀ tí wọn ṣe ní ìpínlẹ̀ Ondo ta ààrẹ lọ́rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad

Aarẹ Buhari wa gboriyin fun gomina Akeredolu fun iṣẹ akanṣẹ naa ti o gbe ṣe ni ipinlẹ naa, bẹẹ lo si ki ku oriire fun ayẹyẹ ọdun kẹta lori oye.