Sagamu: Ògo ọjọ́ iwájú ìdílé wa ni Kazeem tí àwọn SARS ṣekúpa - Iya Kazeem Tiamiyu

  • Olumide Owaduge
  • Broadcast Journalist
Iyaafi Tiamiyu

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

Àkọlé àwòrán,

O ṣalaye pe ọmọ ọhun kii ṣe onijọgbọn, bẹẹ ni ki i ṣe ọmọ " Yahoo."

Iya Tiamiyu Kazeem ti oṣiṣẹ ileeṣẹ SARS fa ṣababi iku rẹ nilu Sagamu ti sọ pe ogo ọjọ iwaju idile wọn ni ọmọ naa jẹ ko to di pe awọn ọlọpaa dẹmi rẹ legbodo.

Arabinrin naa sọ fun ik iroyin BBC Yoruba to ṣebẹwo si ile wọn ni ilu Sagamu pe ọmọ rẹ ọhun ti ṣeleri oke okun fun oun ki iṣẹlẹ iku ojiji to de ba a.

O ni "Kazeem ti sọ fun mi pe ti oun ba ti ri ṣe daadaa nidi iṣẹ bọọlu pe oun maa mu mi lọ si oke okun."

Àkọlé fídíò,

'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Iyaafin Tiamiyu sọ fun BBC pe ibanujẹ nla ati iṣẹlẹ manigbagbe ni iku ọmọ naa jẹ fun gbogbo ẹbi wọn lapapọ.

O ṣalaye pe ọmọ ọhun kii ṣe onijọgbọn, kii ba eeyan ja ati pe kii ṣe oni jibiti ori ẹrọ ayelujara ti ọpọ mọ si "Yahoo boy gẹgẹ bi awọn Ọlọpaa ọhun ṣe fi ẹsun kan an."

Oríṣun àwòrán, @Official3SC

Iya ọmọ naa sọ siwaju sii pe Kazeem ni afojusun lati di araba nidi iṣẹ bọọlu gbigba to n ṣe ki awọn oṣiṣẹ SARS ọhun to ge ẹmi rẹ kuru.

Àkọlé fídíò,

Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro

O ni "ti Kazeem ba n wo ifẹsẹwọnsẹ bọọlu lori tẹlifisan, o ma n woye ọjọ iwaju rẹ, to si ma n sọ pe ibi giga ti oun n lọ niyẹn."

Iya Kazeem tẹsiwaju pe "Gbogbo igba ti ọmọ mi ba lọ gba bọọlu ni mo ma n lọ wo ti papa iṣere naa ko ba jina ju, nitori o ma n jẹ iwuri funmi ti mo ba n wo o, ṣugbọn wọn ti gba ọmọ naa lọwọ mi."

Tiamiyu Kazeem ni ọkọ oju popo kọlu, leyi to yọri si iku rẹ lẹyin ti iroyin ni awọn ọlọpaa SARS ti i jabọ kuro ninu ọkọ wọn ni ọna Abeokuta-Sagamu lọjọ Satide.

Ko to di oloogbe, Kazeem ni igbakeji balogun ikọ agbabọọlu Remo Stars to wa nipinlẹ Ogun.