#Okadaban: Ìjọba fi páńpẹ́ ọba mú àwọn àkàndá tó fẹ̀họ́nú hàn ní Eko

Lagos Ban

Oríṣun àwòrán, JEI

Àkọlé àwòrán,

Awọn akanda eniyan naa n pe fun ijọba lati da kẹkẹ maruwa pada nitori atijẹ ti nira fun wọn ni ipinlẹ Eko.

Awọn akanda eniyan to n wa kẹkẹ ni ipinlẹ Eko ti fẹsun kan ijọba Eko wi pe wọn ti awọn adari wọn mọle nitori wọn ṣe ifẹhọnu han.

Ileeṣẹ ajafẹtọ awọn akanda, JEI lọ fi ọrọ naa lede lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori ifẹhọnu han to waye ni ipinlẹ Eko naa.

JEI ni awọn akanda naa ṣe ifẹhọnu han nitori wiwa kẹkẹ naa da iṣoro silẹ fun lati rin ati iṣẹ ajẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, FEI

Wọn ni igbakeji niyii ti wọn n ṣe ifẹhọnu lori igbesẹ ijọba , amọ ti wọn kọ eti ikun si wọn.

Gbogbo igbiyanju wọn lati ba ijọba sọrọ to jasi pabo lo jẹ ki wọn pinnu lati sun si iwaju ile iṣẹ gomina ipinlẹ Eko ni ọjọ ajẹ.

Asalẹ naa ni awọn ọlọpaa wa ko wọn, ti wọn si lọ sọ wọn si atimọle.

Oríṣun àwòrán, FEI

JEI ni awọn ọga awọn akanda naa, Siriki Abubakar ni ijọba ipinlẹ Eko ti gbe lọ si ileejọ fun ẹsun irinkunrin ati awọn iwa ipa.

Oríṣun àwòrán, FEI

Ileeṣẹ ajafẹtọ naa wa fikun pe ijọba tẹ oju ofin awọn akanda to n pe fun ifọrọwerọ pẹlu ijọba mọlẹ lori bi wọn ṣẹ gbegile wiwa kẹkẹ ni ipinlẹ Eko.

Àwọn àkàndá ìpínlẹ̀ Eko ṣèwọ́de lòdì sí bí ìjọba ṣe gbẹ́sẹ̀ lé okada ati keke maruwa

Awọn alabọ ara ipinlẹ Eko ti ṣewọde lodi si bi ijọba ipinlẹ naa ṣe gbẹsẹle keke maruwa ati okada nipinlẹ naa.

Ogunlọgọ awọn eeyan naa ṣewọde lọ si ọfisi gomina ipinla ọhun, Babajide Sanwo-Olu ti wọn si n bere pe ko jade lati ba wọn sọrọ lori ọna abayọ si igbesẹ naa.

Awọn eeyan ọhun gbe awọn kaadi lọwọ ti wọn si n kọrin pe pe ki Sawo-Olu fun wọn ni ẹtọ wọn gẹgẹ bu olugbe ilu Eko.

Wọn ni igbesẹ ijọba lati gbẹsẹ le keke ati maruwa ti mu ki wọn di alairijẹ, ati pe o ti ṣoro fun awọn kan lara wọn lati rin lati ibi kan si omiran nipinlẹ naa.

Ifẹhonuhan yii ni igba keji ti awọn alabo ara nilu Eko yoo ṣe iwọde lodi si bi ijọba ṣe ni ki keke ati okada kogba kuro ni igboro.

Lara awọn alabo ara to n ṣe iwọde naa jẹ awọn to n ṣeṣẹ awakọ keke maruwa.

Ẹwẹ, awọn alabọ ara maa n lo okada lati lọ lati ibi kan si omiran nilu Eko, nitori o ṣeeṣe fun okada lati lọ gbe wọn lẹnu ọna ile wọn.

Àkọlé fídíò,

Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro