Lagos Business: Ológun kan àtàwọn ọlọ́jà kojú ìjà sí àwọn òṣìṣẹ́ Káńsù

Soldier Image copyright Punch
Àkọlé àwòrán Ọmọ ologun àti àwọn ọlọja koju ija si àwọn oṣiṣẹ́ Kansu ni Eko

Ọmọ ologun kan koju ìjà si àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alabójutó to n ri si ìmọtótó àgbègbè Ikoyi/ Victioria Island lábẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lásìkò ti wọ́n gba ọjà lóri àwọn to n tajà ni etí títí ni àgbàgbè Bonny Camp.

Ṣááju ni ìjọba ti fi atẹjade kan sita tẹ́lẹ̀ pé wọn yoo maa yide kiri ni àdugbò náà láti rii dáju pe gbogbo ayika ọhun dùn wò.

Bakan náà ni ni àwọn ìgbìmọ ọhun ti lọ kakiri àwọn ibi ti wọn yoo ti ṣiṣẹ ni ọjọ iṣẹ́gun ni abẹ afara to kọju si Bonny Camp, ibi yii gan ni àwọn to n ta ǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ titi náà yàn láàyo gẹgẹ bi olu ilé iṣẹ́ wọn nibi ti wọ́n ti n pín ọja ti wọ́n ba fẹ́ tà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'

Atẹjade náà ni kété ti wọ́n pari abẹwò wọn ni àwọn ọmọ ologun kan ti wọ́n o wọ asọ de wọ́n lọ́wọ́ láti ma gba ọja náà lọ́wọ́ àwọn ti wọ́n n ta.

Àwọn ọmọ ogun ọhun ti àwọn kan wọsọ soja ti awon kan ko si wọ́n ń bere pe àṣẹ wo ni ijọba ni láti maa sọ ǹkan ti yóò sẹlẹ ni àgbègbè àwọn ọmọ ologun ti wọ́n si bẹ̀rl si ni lú gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìgbìmọ náà ti wọ́n ri.

Èyí si lo fun àwọn to n t ọja náà ni ànfani láti maa lẹ òkò àti àwọn ǹkan to le panilára mọ àwọn òsìsẹ́ ìjọba náà lanu iṣẹ́ wọ́n.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ọmọ ologun àti àwọn ọlọja koju ija si àwọn oṣiṣẹ́ Kansu ni Eko

" Iroyin ni wan gb]iyànju láti gba ẹrọ ìyàwòràn oniroyin ti o tẹle àwọn ò[sìsẹ́ náà ti wọ́n si lu ọkàn lára àwọn oloye ìgbìmọ náà ti ẹ̀rọ il'éwọ rẹ̀ si tun bàjẹ pẹ̀lú

Alaga ìgbìmọ̀ náà Ọgbẹ́ni Tunji Bello, fi ìbànujẹ rẹ̀ han lori ìgbésẹ̀ àwọn ọmọ ologun náà.

Ọgbẹ́ni Bello to jẹ kọmisọna fun ọ̀rọ̀ ayika àti àlumọni ilẹ̀, sàlàye pe àwọ́n ti se gbogbo ǹkan to le fa èdè aiyede mọlu tẹ́lẹ̀ nitori ìdí èyi si ní àwọn ṣe fi àwé ránṣẹ́ si gbogbo àwọn ẹka ilé iṣẹ́ ọmọ ologun ti ọ̀rọ̀ náà yóò kan. lágbègbè Ikoyi àti V.I.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro