Kazeem Tiamiyu: Mo fọṣọ, fọ ilẹ̀, ta omi tútù láti fi tọ Kazeem àtàwọn tó kù - Òbí Kazeem

"Kò sí ibi tí Kazeem ti lọ gbá bọ́ọ̀lù nítòsí tí mi ò ni lọ láti wo bọ́ọ̀lù náà, Ọlọhun dẹ maa n gba fun wọn".

Nigba ti BBC Yoruba ṣe ibẹwo si awọn obi Kazeem Tiamiyu, agbabọọlu Remo Stars ti ipinlẹ Ogun ti wọn pa laipẹ yii, ṣe ni ọrọ iwunilori nipa oloogbe naa n pe ara wọn ranṣẹ.

Iya Tiamiyu, Selimotu Tiamiyu ni "Kazeem fọkàn mi balẹ̀ pé a máa gbàgbé ìṣẹ́ àti òṣì láyé wa. Bi mo ba n pa itan fun wọn pe mo fọṣọ, fọ ilẹ̀, ta omi tútù láti fi tọ Kazeem àtàwọn ọmọ tó ku, Kazeem a ni ki n fọkàn mi balẹ̀ pé a máa gbàgbé ìṣẹ́ àti òṣì láyé wa".

Arabinrin Selimotu ni ọmọ ohun ti maa n sọ fun oun pe awọn ko ni gbe lorilẹede Naijiria, o ti pinu lati mu mi lọ oke okun.

Baba Kazeem, Tiamiyu Fasasi ni "ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni Kazeem sọ fún mi pé orílẹ̀èdè Sweden fìwé pè é láti wá gbá bọ́ọ̀lù".

Iroyin ti mu inu gbogbo wọn dun to bẹẹ ti baba sọ fun ọmọ rẹ pe apa Ọlọrun a gbe gbogbo ẹ̀.

Ẹwẹ, awọn obi rẹ ni awọn n bere fun idajọ ododo latọwọ ijọba.