Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Iṣẹ agbodegba ọja ipolowo ọja ni Ajikẹ (kii ṣe orukọ rẹ gangan) ro pe oun gba lọwọ ọkọ ọrẹ rẹ, Pẹlumi.

Labakẹ to jẹ ọrẹ Ajikẹ lo muu mọ Pẹlumi to jẹ ọkọ Labakẹ lori ọrọ ati baa rii iṣẹ. Iṣẹ naa bọ sii lootọ. Amọṣa iṣẹ yii lo yii itan igbesi aye rẹ pada.

Ohun mẹta ni koko ti iroyin kayeefi BBC News Yoruba ti oṣu yii ba jade.

Akọkọ, ka finu wenu, ka funni niwọ jẹ.

Ekeji ni itankalẹ iroyin ofege eyi to n fa ipalara fun gbogbo mutumuwa.

Ẹkẹta ni aṣa karaalu maa fi idajọ ofin sọwọ ara wọn.

Iṣẹ yii ran Ajikẹ atawọn akẹgbẹ rẹ mẹta de ẹnu ibode ọrun. Bi o tilẹ jẹ wi pe ọkan ninu wọn pada jade laye nitori atunbọtan iṣẹ naa, Ajikẹ ṣalye ohun toju ri ati bi Pẹlumi to gba wọn si iṣẹ ti wọn fi lu odindi ilu kan ni jibiti owo ẹgbẹlẹgbẹ naira tun ṣe bẹrẹ si ni dun mọhurumọhuru mọ ọ debi pe fidio ihoho oun atawọn ọmọbinrin yooku di eyi to fọnka ori ayelujara.