Restructuring: Obasanjo gbóṣùbà fáwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lórí àgbékalẹ̀ Amotekun

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo

Aarẹ ana ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti kesi awọn asaaju lati tete tẹti si igbe ọpọ ọmọ Naijiria to n pe fun eto atunto orilẹede yii, ko to di pe wọn n se amusẹ rẹ funra wọn.

Oloye Olusegun Obasanjọ pe ipe atunse yii nilu Eko lasiko akanse eto idanilẹkọ kan ti wọn se niranti asaaju ẹgbẹ agbarijọpọ ọmọ bibi Oodua, Oloye Frederick Fasheun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obasanjọ wa fi ewe ọmọ mọ awọn ọmọ aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari leti pe to ba kọti ikun si atunse ati atunto orilẹede wa lasiko yii, afaimọ ki omi ma ti ẹyin wọ igbin lẹnu, tori yoo lẹyin, bii oku iya jọjọ.

Bakan naa ni Obasanjo n fika hanu lori ipo to mẹhẹ ti eto aabo Naijiria wa bayii, pẹlu afikun pe se ni eegun ẹyin ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram n le si lati ọdun mejila sẹyin, kaka ki ewe agbọn wọn si dẹ, ko ko ko lo n le si.

O ni orilẹede yii ko tun lee bọ sinu ogun abẹle miran lasiko yii nitori pe ko ni lee bọ ninu rẹ bii ti akọkọ, ina eesi ko si tun yẹ ko jo Naijiria lẹẹkeji nidi ogun abẹle.

Àkọlé fídíò,

Hero Tortoise: Ìjàpá 14 ni wọn yà sọ́tọ̀ láti bí Ìrère 2000, kí ìran wọn má baà parun

Obasanjọ wa se kare, mo gba fun yin si awọn gomina to wa nilẹ Yoruba fun agbekalẹ eto alaabo Amotekun, pẹlu afikun pe ko si ẹkun kankan ni Naijiria ti yoo lagbara lati da ẹkun miran to ba fẹ yapa duro, tijọba ko ba tete wa nkan se nidi eto atunto orilẹede yii.