Dan Price: Mò ta ilé méjì, dín owó oṣù mi kù pẹ̀lú $1m láti leè sanwó oṣù gọbọi fáwọn òṣìṣẹ́ mi

Dan Price

Oríṣun àwòrán, Gravity

Ohun to kọju s'ẹnikan, Yoruba bọ wọn ni ẹyin lo kọ si ẹlomiran.

Eyi lo difa fun arakunrin kan lorilẹede Amẹrika to jẹ oludari ileeṣẹ kaadi isanwo Gravity Payments, to buwọlu sisan owo oṣu to kere ju, tii ẹgbẹrun lọna aadoje dọla, gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ fawọn osiṣẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọdun 2015 lo gbe igbesẹ yii lori ọgọfa osisẹ to n ṣiṣẹ labẹ rẹ, ti oun gan alara si yọ miliọnu kan dọla kuro ninu iye owo oṣu rẹ.

Lẹyin ọdun marun to gbe igbesẹ yii, o ṣi n san owo yii fawọn oṣiṣẹ rẹ lai yẹ kuro lori rẹ.

Ohun to mu Dan Price ṣe bẹẹ ni igba to mọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ, Valerie ko ri owo ile rẹ san, ọkunrin naa si jẹ alakikanju oṣiṣẹ labẹ rẹ.

Iṣẹlẹ yii mu inu bi Dan Price, to si bẹnu atẹ lu bi ile aye ko ṣe rọrun fawọn eeyan kan. Lẹyin to kọminu lori ọrọ yii, o ri pe oun gan wa lara awọn ti ko mayedẹrun fawọn eeyan.

Toun ti pe Dan jẹ olowo tabua, ohun to ṣẹlẹ si oṣiṣẹ rẹ Valerie yii lo ṣe okunfa bo ti ṣe mọ pe awọn ti nkan ko dẹrun fun pọ lawujọ.

Idi re e ti Price fi pinnu lati mu alekun ba iye owo oṣu awọn to n ṣiṣẹ labẹ rẹ, ni ileeṣẹ Gravity Payments.

Lẹyin to ṣe atupalẹ iye owo ti yoo mu eeyan gbe igbe aye igbadun l'Amẹ́rika, Dan pa ọkan pọ pe ẹgbẹrun lọna aadọrin ni yoo to lowo oṣu to kere julọ fawọn osisẹ oun.

O ni eleyi mu adinku ba owo oṣu oun gan funra ara oun, ti oun si ta ile oun mejeeji. Igba to ṣe awọn eto wọn yii tan, lo ba fi ọrọ to awọn oṣiṣẹ rẹ leti.

Lati igba to si ti gbe igbesẹ yii, ida mẹwa ninu ida ọgọrun awọn oṣiṣẹ rẹ lo ti nile lori, yatọ si ida kan wọn to nile lori tẹlẹ, ki o to fi owo kun owo osu wọn.

Ni bayii, Price ti di ajafẹtọ ẹni to n polongo nipa ibadọgba igbe aye laarin awọn eeyan nilẹ Amẹrika.