Foluke Daramola Salako sọ̀rọ̀ nipa iku Pa Kasumu

Foluke Daramola Salako sọ̀rọ̀ nipa iku Pa Kasumu

O ti pẹ diẹ ti ipenija ailera ti n ba Pa Kasunmu finra.Ipapoda wọn dun mọ wa nitori bi isinmi lo jẹ.

Ọrọ re e ti gbajugbaja oṣere tiata Yoruba Foluke Daramola Fatoki sọ nipa agba oṣere nii Kayode Odumosu ti gbogbo eeyan mọ si Pa Kasumu to jade laye lọjọ Aiku.

Ninu ọrọ rẹ, Foluke Darams ni ''Pa Kasumu jẹ olootọ eeyan ti wọn si jẹ alaanu eeyan''

O ni ni nkan bi ọdun mejila sẹyin lawọn eeyan kọkọ da owo jọ fun Pa Kasunmu lati lọ fi gba itọju ni India.

''Nigba to di ana ni wọn gbe wọn lọ si ile iwosan pe ara wọn ko ya.Nigba ti wọn de, wọn lawọn fẹ lọ si ile igbọnsẹ.Wọn dari de ni wọn ba gbẹmi mi''

Foluke ni Pa Kasumu ati awọn agba oṣere bi tiẹ kopa ninu ere lalai fi ti ọjọ alẹ ṣe.

O ni ifẹ ere tiata lo mumu laya wọn ju kiko ọrọ jọ ti eleyi si pada wa mu inira ba wọn nigba ti wọn ko ribi kopa ninu ere mọ.

O wa rọ awọn to n dari ere lati yago fun fifi atike sọ awọn ọdọmọde oṣere darugbo ninu ere.

O ni iru iwa bẹ a ma kọdi anfaani to pọ lara awọn agba oṣere ti wọn darugbọ ṣugbọn ti ọpọlọ wọn ko jọba.

''Aikopa ninu nkan ti eeyan ba mọ ṣe bi apẹre ere tiata fawọn agba oṣere jẹ nkan to ma n fa irẹwẹsi ọkan fawọn toba ti darugbo''

''Mo rọ awọn akẹgbẹ mi lati ma lo awọn agba oṣere wa ninu ere daaada''

Foluke bakanna dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti o nawọ iranwọ si Pa Kasumu ki o to jade laye.