Coronavirus: Mínísítà ní àwọn èèyàn tí wọ́n kó pamọ́ ní Eko àti Plateau kò ní àrùn náà

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire ti sọ pe, awọn ọmọ orilẹ-ede China mẹrin ti wọn ko pamọ fun itọju arun Coronavirus nipinlẹ Plateau, ko ni arun naa.

Osagie sọ fun awọn akọroyin nibi ipade ita gbangba kan to waye n ilu Abuja pe, ko si ẹnikẹni lara awọn eeyan naa to ni arun ọhun, lẹyin ti wọn ṣayẹwo wọn ni ileeṣẹ ijọba to n ṣetọju arun, NCDC.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Plateau ti kede pe, o ṣeṣe ki awọn eeyan naa ni arun Coronavirus lẹyin ti wọn de si Naijiiria lati China, to si fi wọn si apamọ fun ayẹwo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tẹsiwaju pe, ipinlẹ naa ti fi awọn ọmọ orilẹ-ede China ọhun sabẹ itọju, nibi ti awọn eleto ilera yoo ti bojuto wọn fun ọjọ mẹrinla fun ayẹwo siwaju sii.

Ẹwẹ, Osagie ni ko tii si ẹni kankan to tii lugbadi Coronavirus ninu gbogbo awọn eeyan to ṣabapade okunrin ọmọ orilẹ-ede Italy, to ko arun ọhun wọ Naijiria nilu Eko.

O ni "Gbogbo awọn eeyan to pade ẹni naa ni ipinlẹ Eko ati Ogun ni wọn ti n gba itọju lọwọ, ṣugbọn ko tii si ẹnikẹni lara awọn eeyan naa to tii lugbadi arun naa."

Oríṣun àwòrán, @InsideOjodu

Minisita ọhun wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati mase bẹru lakoko yii, nitori ijọba apapọ n ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe arun naa ko tan kalẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijira lati mu imọtoto ni pataki, lati maa fọ ọwọ wọn pẹlu ọsẹ, ati lati jina rere ni nnkan bii iwọn eṣẹ bata marun, si ẹni to ba nsin tabi wukọ layika wọn.

Àkọlé fídíò,

Oman Returnees: Ọ̀kan lára àwọn obìnrin méjì náà ní òun ṣiṣẹ́ ọdún kan láì mú ₦5 padà wálé

Osagie pari ọrọ rẹ pe, ki awọn eeyan maa bo imu ati ẹnu wọn pẹlu igbọnwọ, ki wọn si rọ awọn eeyan to ba sun mọ wọn lati ṣe bẹẹ pẹlu.