Gómìnà Oyetọla tí yi ìlànà ètò ẹ̀kọ Rauf Aregbesola pada

Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Gómìnà Oyetọla tí yi ìlànà ètò ẹ̀kọ Rauf Aregbesola pada

Lọ́sẹ to kọja ni àwọn ọmọ igbimọ ti gomina ìpinlẹ̀ Osun Gboyega Oyetola gbékalẹ̀ láti ṣe àyẹwo àwọn ìlànà èto ẹkọ gomina àná Rauf Aregbẹsọla, gbé àbájade ìwádìí wọ́n wá.

Abájáde náà nàka si àwọn koko mẹ́rìnlélógun gbòógi to nílò sàgbéyẹwò eyi to fi mọ mímú àyípada ba wíwọ aṣọ ilé iwé kan náà jákejádo gbogbo ìpínlẹ̀ Osun.

Ẹ̀wẹ̀, lọ́nìí ọjọ keji, oṣù kẹta ọdun yìí ni gómìnà lásìkò ìpàdé ìgbìmọ aláṣẹ́ ìjọba ni wọ́n ti pa ohùn pọ láti gba aba ìgbìmọ ìwádìí wọ́n wọlé, paàpàá jùlọ lóri èyi to jẹ mọ ìlàna ẹkọ ni ìpinlẹ̀ Osun.

Ti ẹ o bá gbàgbé ìgbìmọ ìwádiìí ti Gomina Gboyega Oyetola gbe kalẹ̀ ni ọjọgbọ́n Olu Aina jábọ rẹ̀ fun Gomina ni ọ̀ṣẹ̀ to kọja ti wọ́n si gba ìjọba ni ìmọ̀ràn láti dá ìwọ̀sọ àwọn akẹkọọ pada si bi wọ́n se wà tẹ́lẹ̀.

Wọ́n fi kun pe o ṣe pataki ki wan pada si ìlàna ẹkọ 9-3-4 gẹ́gẹ́ bi àwọn onímọ ètò ẹkọ ṣe gbé kalẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Pa Kasumu: Lere Paimo ní àìrìríjẹ́, àìrímú tàbí ìrònú má a ń jẹ́ kí ọjọ́ ogbó dagun