UCH: Olùdarí ilé ìwòsàn náà ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ àwọn ẹlẹ́yinjú àànú láti borí ìṣòro owónàá

Awọn dokita to n se isẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, UCH

Awọn alasẹ ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti Ibadan, UCH ti figbe bọnu pe ara ko rọ okun, bẹẹ ni ko rọ adiẹ nile iwosan naa, nitori ẹrọ amunawa to to marundinlọgọrin ni wọn n lo lati sisẹ isegun.

Oludari eto isegun nile iwosan naa, Ọjọgbọn Jesse Abiọdun Ọtẹgbayọ lo sisọ loju ọrọ yii nibi eto kan ti wọn fi n sami ayẹyẹ ọdun kan rẹ lọọfisi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọtẹgbayọ ni isoro nla kan gboogi to n ba ibudo ẹkọsẹ isegun Oritamẹfa naa finra ni aisi ina ọba to duro re, bẹẹ si ni ipenija nla ni eyi jẹ fun iwadi imọ isegun, idanilẹkọ ati ipese iwosan to ye kooro.

Oríṣun àwòrán, UCH

"A maa n pa owo to to igba miliọnu naira wọle losoosu, ko si yẹ ka foju fo eyi pẹlu iye ta n na lori epo disu, atunse awọn ẹya ara jẹnẹratọ ta n lo ati owona lori awọn eroja miran ta nilo fun isẹ wa. Mo si lee ni owo yii ko to na rara, o si se ni laanu pe a ni awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ to lee fun wa lẹbun owo lati fi kun owo ta n pa wọle."

Oríṣun àwòrán, UCH

Bakan naa ni oludari eto isegun ni UCH salaye pe ipese ina ọba jẹ pataki si awọn nitori bo ti se pataki to fun ipese eto ilera ti wọn n se, paapa fun isẹ fawọn abẹ alaisan.

"Afojusun wa ni lati pese awọn imọ ẹrọ to lee se awari ọpọ arun to n tan kalẹ lorilẹede Naijiria, ka si se agbende iwosan aisan ọkan ta n se tẹlẹ, eyi ta ti pa ti tẹlẹ, pada. Bakan naa la fẹ ri daju pe iwosan aisan kidinrin taa yọ lati ara ẹnikan fun ẹlomiran, eyi taa se laipẹ yii, n tẹ siwaju."

Àkọlé fídíò,

Làá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus

Amọ o wa fi ika hanu pe laisi ipese ina ọba to jiire, wahala lee de, tabi ki ohun gbogbo dẹnu kọlẹ ti awọn ẹrọ amunawa tawọn n lo ba bajẹ, nitori aisi ipese ina ọba to ye kooro.