Amotekun: Àwọn aṣòfin Oyo fí aṣọ́ Amotekun, ìfúnpá àti gbérí ọdẹ́ buwọ́lu àbádòfin Amotekun

Aworan awon asofin Oyo

Bi iṣẹ ko ba pẹni ẹnikan kii pẹ'ṣẹ, ni awọn ile asofin ipinlẹ Oyo ati Ogun fi bibuwọlu abadofin idasilẹ Amọtẹkun ṣe.

Lọjọ iṣẹgun yii ni awọn mejeeji joko jiroro lori abadofin naa, ti wọn si buwọlu ofin to gbe idasilẹ ikọ alaabo naa silẹ nipinlẹ wọn.

Ṣaaju asiko yii ni awọn ijọba ilẹ kaarọ o jiire ati ijọba apapọ ti fẹnu ko si pe, ki awọn ipinlẹ kọọkan pada lọ fi ofin gbe idasilẹ Amọtẹkun silẹ ni ipinlẹ wọn.

Yatọ si ipinlẹ Eko ti o mu atunṣe ba ofin to ṣe idasilẹ ikọ alaabo Neighbourhood Watch, ti o ti wa nilẹ tẹlẹ, awọn ipinlẹ to ku ṣẹṣẹ bẹrẹ igbesẹ lati fi ofin de idasilẹ Amọtẹkun lagbegbe wọn ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asọ Amọtẹkun lawọn aṣofin Oyo wọ wa si ile

N ṣe ni awọn aṣofin ile aaṣofin Oyo ko anko wọ aṣọ to jọ awọ Amọtẹkun, wa si ile lati le fi ifarajin wọn han lori sisọ abadofin yii di ofin.

Bẹrẹ lati olori ile to fi dori awọn aṣofin to ku, bi wọn ti ṣe n wọ dansiki, lawọn miran de gberi ọdẹ sori.

Koda agbọpa ile gan ko gbẹyin, ti oun naa si fi asọ amọtẹkun gbe ọpa ile lọwọ, ti wọn si tun wọ ifunpa si apa wọn.