Gbajabiamila: Mò ń ṣe ọjọ́ ìbí fún màmá mi ní Dubai àmọ́ kìí ṣe owó ìlú ní mo ń ná

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @femigbaja

Olori ile asoju-sofin, Femi Gbajabiamila ti mu igbe bọnu pe kii se owo ilu ni oun fi lọ silu Dubai lati se ọjọ ibi fun iya oun.

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ Gbajabiamila feto iroyin, Lanre Lasisi fisita wa salaye pe, kikida awọn mọlẹbi ati ọrẹ timọtimọ nikan ni wọn ko lọ sibi ayẹyẹ naa, ti wọn ko si to ọọdunrun niye, gẹgẹ bi iroyin kan ti sọ.

"Lootọ ni olori ile asofin ati awọn mọlẹbi rẹ wa ni Dubai lati se ayẹyẹ ọjọ ibi mama agba, Alhaja Lateefat Olufunkẹ Gbajabiamila to pe ẹni aadọrun ọdun loke eepẹ, mama naa si ni iya lori ile asoju-sofin nilẹ wa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A si fẹ fi da yin loju pe ko si oloselu tabi asofin kankan nilẹ wa to peju sibi ayẹyẹ naa, kikida awọn mọlẹbi ati ọrẹ timọtimọ lo wa nibẹ, ti a ko si lo owo ilu kankan.

Àkọlé fídíò,

Strongest Teeth: Tajudeen ní èèyàn ló kù tí òun fẹ́ máa fi eyín gbé

Laipẹ yii ni iroyin naa gbalẹ pe tijo tilu ni olori ile asoju-sofin fi se ayẹyẹ ọjọ ibi mama rẹ nilu Dubai, eyi ti wọn lo bẹrẹ ni ọjọ keji osu kẹta ọdun yii, ti yoo si pari ni ọjọ kẹwa osu kẹta yii kanna.

Iroyin naa ni, o seese ki Gbajabiamila na to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira lori ayẹyẹ naa, ta ba wo iye awọn eeyan to ko lẹyin lọ sibẹ.