Oshiomhole: ilé ẹjọ́ gíga míì ti tako àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ní kí Oshiomhole lọ rọọ́kún nílé

Adams Oshiomhole

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Kano ti fọwọ rọ idajọ ile ẹjọ giga Abuja to ni ki alaga ẹgbẹ APC Adams Oshiomole yẹba ṣẹgbẹ kan gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.

Bẹẹ ni adajọ Lewis Allagoa to gbe idajọ yi kalẹ paṣẹ ki ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria pese awọn ẹṣọ alaabo ti yoo tẹle Adams Oshiomole lọ si ọfiisi rẹ pada.

Lọjọbọ ni aṣẹ yi waye nilu Kano.

Wahala edeaiyede abẹle to n waye ni ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba orilẹede Naijiria, APC gbinaya gba oju opo ibomiran yọ ni Ọjọbọ nigba ti ile ẹjọ giga kan ni ilu Abuja gbe idajọ kalẹ pe ki alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Adams Oshiomhole o yẹba naa atipe ko gbọdọ pe ara rẹ ni alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ yii titi di igba ti ẹjọ lori boya o lẹtọ lati jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu naa yoo fi yọri.

Amọṣa Ọgbẹni Issa Onilu to jẹ alukoro apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣalaye pe ki ẹnikẹni maṣe sọ pe wahala abẹle n bẹ laarin ẹgbẹ oṣelu APC.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba lori idajọ to yẹ aga mọ alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Ọgbẹni Issa Onilu ṣalaye pe lootọ o lee jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lo gbe alaga, iyẹn Adams Oshiomhole ati ẹgbẹ oṣelu naa lọ si ile ẹjọ, sibẹ kii ṣe ọmọ igbimọ majẹobajẹ tabi igbimọ iṣakoso to ga julọ ni ẹgbẹ oṣelu naa.

O ni nipasẹ bẹẹ, a ko lee pe e ni edeaiyede abẹle lẹgbẹ oṣelu naa.

Àkọlé fídíò,

Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo

Lootọ, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC , Adams Oshiomhole ni oun ti gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, bẹẹ ni agbẹnusọ rẹ, Simon Egbegbulem yọju rẹ sita ninu atẹjade kan to fi ranṣẹ si akọroyin BBC news pe awọn ti kọwe kotẹmilọrun lati tako idajọ naa.

Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu naa ti ni awọn yoo tẹle ilana ofin lori ọrọ naa.